Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, c87e81lzqqvo
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Published

Gbọna, ki lo n ṣẹlẹ ni Ijebu-Ode ati Ijebu-igbo ti awọn akẹkọọ fi n daku rọgbọndan?

Bẹẹ laa bi ni o, mo gbọ pe oorun buruku lo dede burẹkẹ nibẹ, koda ile ẹkọ mẹta ọtọtọ ni ọrọ naa kan

Ẹhn...ẹhn...

A gbọ pe iṣẹlẹ yii ni igba kẹrin ti irufẹ oorun buruku bayii yo ṣẹyọ nipinlẹ Ogun

Hmmmmmm.....

Ẹkunrẹrẹ wa loju opo BBC Yoruba

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Adẹrinpoṣonu ori ayelujara nni, Samuel Perry, ti ọpọ mọ si Broda Shaggi

Ti tu pẹrẹrẹ bi ọta aṣita ibọn ṣe ba a nibi to ti lọ polowo ọja fun ileeṣẹ kan

O ni itan ni ibọn naa ti ba oun ti ẹjẹ si da ṣorọṣoro

Shagi ni ọpa loun fi n rin bayii amọ ki awọn ololufẹ oun maa reti ipadabọ Abuja oun laipẹ

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ati gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Olusegun Mimiko

Ti juwe olori ẹgbẹ Afenifere to di oloogbe, pa Reuben Fasoranti gẹgẹ bii ẹni to fi ipa rere lelẹ fun awọn oloṣelu

Ọro yii lo jẹyọ lasiko ti wọn ṣabẹwo sile oloogbe naa niluu Akure

To ba fẹ mọ ẹkunrẹrẹ