Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Wo ìgbà mẹ́rin tí afẹ́fẹ́ òórùn burúkú ti ṣe àkóbá fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ l'Ogun àti igbésẹ̀ ìjọba
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ afẹfẹ buruku kan to n ran ọpọ awọn akẹkọọ lọ sile iwosan lojiji ṣi n jẹ kayeefi fun gbogbo olugbe ipinlẹ Ogun.
Ọjọru, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa. ọdun 2026 ni iṣẹlẹ ijamba afẹfẹ miran tun waye niluu Ijebu-Ode ati agbegbe rẹ, to fi mọ Ijebu-Igbo.
Eyi ni yoo jẹ igba kẹrin ti ijamba naa yoo waye laaarin oṣu mẹfa sira wọn, ṣugbọn ti ijọba ipinlẹ naa ko tii ri ọna abayọ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́
Nigba ti iṣẹlẹ akọkọ yoo waye, kayeefi nla lo jẹ, pẹlu bi awọn araalu ṣe pariwo sita pe nnkan buruku wọle tọ wọn.
Fun ọpọ awọn akẹkọọ ati gbogbo awọn to kagbako oorun buruku yii lọjọ kinni, oṣu Kẹrin, ọdun 2026, opin aye ti de ni wọn lero.
Ile-ẹkọ girama ti Our Lady of Apostle to wa lagbegbe garaaji Epe niluu Ijebu-Ode ni oorun buruku ọhun ti kọkọ ṣọṣẹ.
Awọn akẹkọọ ti ko din ni ọgbọn, ati olukọ kan ni iroyin fi to wa leti wi wọn sare gbe digbadigba lọ si ile iwosan ijọba lati doola ẹmi wọn.
Ko pẹ ti wọn lawọn akẹkọọ naa ṣẹṣẹ wọle sinu kilaasi wọn, lati bẹrẹ eto ẹkọ ọjọ naa, ni wọn sọ pe oorun buruku yii deedee gbilẹ, ti ọpọ ko si le mu mọra.
Bi awọn kan ṣe n pokaka iku, bẹẹ lawọn miran n bi, ti ninu wọn si tun daku, eyi lo jẹ ki awọn alakoso ile-ẹkọ naa pariwo sita fun iranlọwọ.
Ṣugbọn ṣa, ohun ti ọpọ awọn eeyan n sọ nigba naa ni pe afẹfẹ ọhun lo jẹyọ lati inu yara idansọ awọn onimọ sayẹnsi ile iwe ẹkọ naa, lasiko ti awọn akẹkọọ n po kẹmika papọ.
Nigba naa, Kọmiṣanna feto ayika, Ola Oresanya fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si ni awọn ko tii le sọ pato ohun to ṣokunfa oorun buruku.
Ọjọ keji ni ijọba ti paṣẹ pe ki wọn ti ile-ẹkọ naa pa, titi digba ti iwadii yoo fi pari, ati pe ki wọn tọju gbogbo awọn to farakaaṣa naa lai gba owo lọwọ wọn.
Oresanyan sọ pe ijọba ipinlẹ Ogun yoo ṣe iwadii lati mọ kulẹkulẹ naa, ati pe ki wọn ti ilẹkun ile-ẹkọ naa pa, titi digba ti iwadii yoo fi pari.
Yatọ si eyi, Gomina Dapo Abiodun tun paṣẹ pe ki wọn ṣi yara itọju ọfẹ silẹ ninu ile iwosan ijọba ti ijọba Ode, nibi ti awọn eeyan to ba tun fara kaaṣa oorun buruku naa yoo ti gba itọju.
Ìṣẹ̀lẹ̀ kejì
Ohun to ṣẹlẹ yii ni awọn eeyan ṣi n sọrọ nipa rẹ lọwọ, to si fẹẹ dabi ẹni pe awọn eeyan ti gbagbe nipa rẹ, ati pe iru nnkan bẹẹ ko tun le ṣẹlẹ mọ.
Ṣugbọn ṣa dede ni afẹfẹ oorun buruku ọhun tun suyọ lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, to si jẹ pe awọn to kagbako lọjọ naa le lọgọrun kan.
Ọpọ awọn akẹkọọ, olukọ ati ọpọ ile-ẹkọ ni afẹfẹ oorun buruku naa tan de, to si mu ki wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan ijọba to wa niluu Ijebu-Ode.
Nigba naa, ohun ti a gbọ ni pe nigba ti ọgba ile iwosan ijọba ko fẹẹ gba awọn eeyan mọ, lo jẹ ki wọn gbe awọn miran lọ sawọn ile iwosan aladani fun itọju.
Lara awọn ile-ẹkọ ti afẹfẹ oorun buruku naa wọ ni Anglican Girls Grammar School, Obalende, ati Our Lady of Apostles Secondary School, to wa ni garaaji Epe.
Bi oorun yii ṣe gbilẹ ni awọn akẹkọọ ti bẹrẹ sii kigbe inu rirun, ara rirẹ, ailẹ min daadaa, koda ti awọn miran tun daku.
Ariwo 'ẹ gba wa', ni wọn lawọn to wa lagegbe naa fi sare wọle lati ṣe iranwọ fun awọn akẹkọọ ati olukọ naa.
Ijọba ipinlẹ Ogun lọjọ keji jẹ ko di mimọ pe ohun ti ṣawari kẹmika kan niluu Ijebu-Ode, eyi ti wọn lo yi agbegbe ẹgbẹrun mẹtala ataabọ ka.
O sọ pe gbogbo awọn ileeṣẹ tọrọ naa kan ni wọn ti ṣawari ibi ti afẹfẹ oorun buruku ọhun ti n wa, ati pe nigba to ba dun gbamu, ni oorun naa yoo jade.
Ṣugbọn ṣa nigba to di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu aa, Kọmiṣanna feto ilera, Tomi Coker fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn eeyan to lugbadi afẹfẹ buruku naa lo ti wa ni alaafia, ti wọn si ti pada sile.
Ìgbà kẹ́ta
Ọjọ buruku, eṣu gbomimu lọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun yii tun jẹ nigba ti iṣẹlẹ miran tun ṣẹlẹ.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn n beere pe 'ṣe kii ṣe pe opin aye ti fẹẹ de', pẹlu bi oorun ọhun tun ṣe sọ awọn ti ko din ni mọkandinlaadọrun dero ile iwosan.
Itọju pajawiri ti awọn oṣiṣẹ eleto ilera ile iwosan ijọba niluu Ijebu Ode ṣe fawọn eeyan, lo jẹ ki pupọ wọn pada sile nigba ti wọn gbadun.
Ọpọ ile-ẹkọ bii Our Lady of Apostles Secondary School; Anglican Girls Grammar School; Titilayo Agbaje Comprehensive High School ati Ifesowapo Comprehensive High School niluu Imosan; St Anthony Grammar School to wa niluu Ijebu-Imushin, ati awọn miran ni oorun naa ya wọ.
Kọmiṣanna feto ayika, Ola Oresanya tun sọrọ nigba naa, to si ni ẹrọ ayẹwo afẹfẹ gaasi ti ijọba gbe kalẹ ti ṣawari ibi ti afẹfẹ buruku naa ti n wa.
Lẹyin eyi ni ijọba fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ko gbogbo awọn akẹkọọ ile-ẹkọ ti oorun naa wọ kuro fun igba diẹ, titi iwadii yoo fi pari.
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin ńkọ́?
Iṣẹlẹ to ṣẹlẹ l'Ọjọru, ọsẹ yii ni ẹlẹẹkẹrin iru rẹ ti yoo waye, ti ko sit ii sẹni to le fidi rẹ mulẹ boya iṣẹlẹ naa ni yoo jẹ ikẹyin iru rẹ.
Oniruuru ẹbẹ ni awọn araalu, paapaa awọn ara agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti n waye ti n bẹ ijọba ipinlẹ naa, lati dide iranlọwọ to yẹ.
Awọn eeyan sọ pe ọna abayọ ti yoo dẹkun afẹfẹ naa patapata ni awọn n fẹ.
Afẹ́fẹ́ gáàsì burúkú fẹ́ lù àwọn ìlú kan l'Ogun, ọ̀pọ̀ akẹ̀kọ̀ọ́ dèrò iléèwòsàn, aráàlù sọ ohun tó ṣeéṣe kó fàá
Niṣe lọrọ tun di bi o ko le lọ, ki o yago lọna nigba ti wọn sọ pe oorun buruku kan tun suyọ lawọn agbegbe kan niluu Ijebu-Igbo ati Ijebu-Ode, to si ṣe akoba fun ọpọ akẹkọọ.
Awọn akẹkọọ ile-ẹkọ girama ti ko din ni mẹta la gbọ pe oorun buruku naa ti ṣọṣẹ, to si sọ pe ọpọ akẹkọọ ati olukọ di eru ile iwosan.
Iṣẹlẹ yii ni yoo jẹ igba kẹrin iru rẹ to ṣẹlẹ laaarin ọdun 2026, ti ijọba ipinlẹ naa si ti n wa iyanju si i.
Asiko ti wọn ni awọn akẹkọọ naa wa ni yara ikẹkọọ, ni afẹfẹ oorun buruku naa fẹ lu wọn, to si mu ki ọpọ wọn ṣubu lulẹ.
Ijebu-Igbo Girls Grammar School; Anglican Girls Grammar School, to wa ni Ijebu-Ode, Itamerin Comprehensive High School, to wa niluu Ago-Iwoye; Abusi Edumare Girls Grammar School to wa ni Ijebu-Igbo, ati awọn ile-ẹkọ miran ni oorun buruku naa ti ṣọṣẹ.
Kete ti iroyin ti tẹ ijọba ipinlẹ Ogun lọwọ la gbọ pe wọn ti ju agaadagodo sẹnu ọna awọn ile-ẹkọ naa, lati da eto-ẹkọ duro nibẹ.
Kí làwọn aráàlú sọ?
Lara awọn araalu to ba BBC sọrọ nibi iṣẹlẹ naa sọ pe, kii ṣe igba akọkọ ree ti oorun buruku naa yoo ṣọṣẹ fun awọn eeyan, ti wọn si ni ko tii sẹni to le fidi ibi to ti n wa mulẹ.
Ọgbẹni Paul Onogwu, ọkan lara awọn araalu ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ sọ fun BBC pe nnkan bi agogo mẹwaa owurọ Ọjọru, ọsẹ yii ni afẹfẹ oorun buruku naa jade.
Onogwu sọ pe kete ti awọn eeyan, paapaa awọn akẹkọọ naa ti bẹrẹ sii fa oorun naa simu, ni wọn ti bẹrẹ sii ṣubu lulẹ, ti wọn si n pokaka iku.
Ọkunrin naa fi kun ọrọ rẹ pe oorun buruku ọhun lo sọ pupọ awọn akẹkọọ to le ni ọgọrun kan di ero ile iwosan fun itọju.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe ile iwosan ijọba to wa niluu Ijebu-Ode ni wọn gbe ọpọ awọn akẹkọọ naa lọ fun itọju.
"Kọ̀ǹga tí wọ́n ń gbẹ́ ló ń fa òórùn burúkú yìí"
Lara awọn araalu miran tun sọ fun BBC pe nnkan ti awọn ṣakiyesi ni pe awọn kọnga ti awọn eeyan n gbẹ lawọn agbegbe naa lo n fa oorun buruku naa jade, to si n ṣe akọba fun awọn eeyan, paapaa awọn akẹkọọ.
Ẹni naa to kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe awọn ọpa afẹfẹ gaasi kan ti wọn ti ri mọlẹ tipẹ, ṣugbọn ti wọn ti pa ti, lo n gbe oorun buruku ọhun jade, nigba ti wọn ba gbẹ kọnga de ibi to wa.
O sọ siwaju pe ọpọ ile ni wọn ti kọ sori awọn ọpa afẹfẹ gaasi alopati naa, to si ṣoro lati ṣe awari wọn.
Bakan naa, Ọgbẹni Michael Abiodun, ọkan lara awọn obi akẹkọọ ti oorun buruku naa sọ di ero ile iwosan sọ fun BBC pe, oun ti wa pade ọmọ oun nile iwosan ijọba ti Ijebu-Ode.
Ṣe abo to peye wa fun awọn akẹkọọ lagbegbe naa?
Nigba ti BBC News Yoruba kan si ileẹkọ naa lọjọbọ, awọn akẹkọọ ti tun n ba eto ẹkọ wọn lọ nibẹ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn iroyin kan ti jade tẹlẹ pe ijọba ti ti awọn ileẹkọ to wa nibẹ pa, abẹwo BBC sibẹ fihan pe ẹkọ n tẹsiwaju nibẹ. koda a gbọ wi pe awọn akẹkọọ to fara kaasa afẹfẹ gaasi naa, ti wọn ti ko lọ si ileewosan ni wọn ti tu wọn silẹ nileewosan lati pada sile, wọn ko si wa si ileẹkọọ naa lọjọbọ.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileẹkọ naa fi to BBC leti pe awọn n tẹsiwaju pẹlu ẹkọ awọn nitoripe ko si aṣẹ kankan to wa latọdọ ijọba pe ki wọn ti ilẹkun ileẹkọ naa. o ni lootọ awọn akẹkọọ ti wọn ko lọ sileewosan ko wa si ileẹkọọ nitori ilera ara wọn
Ìwádìí bẹ̀rẹ̀
Ni bayii, ijọba ipinlẹ Ogun ti wa sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lori iwadii kikun lati mọ ohun ganan to n fa afẹfẹ oorun buruku naa, ati ibi to ti n wa.
Akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ ati imọ sayẹnsi nipinlẹ naa, Arabinrin Oluwatosin Oloko sọ fun BBC pe otitọ ni iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ti wa lori rẹ.
Oloko fidi rẹ mulẹ pe nigba ti ijọba ba pari iṣẹ iwadii, wọn yoo fi to gbogbo araalu leti nipa abajade iwadii ti wọn ba ṣe.