"Mo rí ìrírí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ bọ́ọ̀lù gbígbá, àwọn èèyàn kò lérò pé mo le di ààyò nídìí bọ́ọ̀lù gbígbà - Harry Kane tó gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or sọ̀rọ̀ akin

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Harry Kane ti di agbabọọlu ọmọ ilẹ gẹẹsi akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ Ballon d'Or lẹyin ti wọn gbe ade agbabọlu to pegede julọ ni agbaye sori Michael Owen lọdun 2001 nibi ayẹyẹ kan to waye nilu London.

Agbabọọlu naa tii se ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Bayern Munich ni ọmọ ilẹ Gẹẹsi karun ti yoo bori.

Awọn agbabọọlu to ti gba ami ẹyẹ ri ni Stanley Matthews (1956), Bobby Charlton (1966), Kevin Keegan (1978 ati 1979) pẹlu awọn miran.

Denis Law tilẹ Scotland lọdun1964 ati George Best tii se ọmọ ilẹ Northern Ireland naa gba ami ẹyẹ lọdun 1968, to si wa lara awọn ọmọ ilẹ United Kingdom ti wọn da lọla.

Agbabọọlu Real Madrid ati France, Kylian Mbappe lo se ipo keji nigba ti Lamine Yamal, agbabọọlu fun Barcelona ati Spain se ipo kẹta.

"Kii se gbogbo eeyan lo le ro eyi, emi gan ko lero pe mo le de ipo yii" Kane lo sọ bẹẹ fun Dazn.

"Mo ri iriri oke ati pẹtẹlẹ, paapaa ni ibẹrẹ isẹ oojọ mi yii. Emi kii se ẹni ti awọn eeyan lero pe yoo di aayo nidi isẹ bọọlu gbigba gẹgẹ bii awn yoku mi"

"Mo wa se suuru, mo si sisẹ kara, ni ọpọ igba, emi ati ọkan mi la dijọ n jiroro, mo si lu aluyọ, mo safihan pe m oni igbagbọ ninu ara mi, mo fi ipinnu ọkan mi han ati igbagbọ mi nipa ara mi.

"Eyi si lo mu mi tẹsiwaju nigba t imo de ipo giga tan, t imo si n mu ilsiwaju ba ara mi lati di agbabọọlu to dara si."

Alakoso ikọ agbabọọlu fun ilẹ Gẹẹsi, Thomas Tuchel kede pe inu oun dun lati ri pe Kane lo gba ami ẹyẹ naa eyi to sapejuwe bii idanilọla nla.

Ọmọọba William, ni tiẹ salaye pe agbabọọlu naa to ti gba bọọlu ri fun ikọ agbabọọlu Tottenham Hotspur jẹ olori ẹgbẹ to dantọ ati agbabọọlu ti ko se fi ọwọ rọ sẹyin.

Kane lo gba ami ayo mọkanlelọgọta wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkalelaadọta to ti kop ani saa ere bọọlu to kọja, eyi si lo ga julọ ti agbabọọlu kan yoo ni, ni saaere bọọlu kan.

To fi mọ awọn ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu nilẹ Gẹẹsi, o jẹ goolu mẹtalelaadọrin ni ifẹsẹwọnsẹ marundinlaadọrin.

Agbabọọlu kansoso ni to n gba bọọlu fun ikọ kan ninu idije liigi to pegede marun nilẹ Yuroopu lo tii gba iru goolu bayi wọle ri nis aa ere bọọlu kan.

Amọ Kane gba ami ẹyẹ Ballon D'or lai gba awọn ami ẹyẹ to se kanka ri nidi ere bọọlu nis aa to kọja, to si fidi rẹmi ninu idije ife ẹyẹ agbaye ati ifẹsẹwọnsẹ to kangun si asekagba ninu idije Champions League.

Ẹka ere idaraya BBC wa se agbeyẹwo idi ti Kane se bori lati gba ami ẹyẹ nla yii , ati bi ko se wọpọ lati jawe olubori lai jẹ pe agbabọọlu naa ti gba ife ẹyẹ ninu idije meji ti a darukọ yii.

Ìtàn tuntun tí Kane fi balẹ̀ lọ́dun 2025 si 2026

Nipa aami ẹyẹ, Kane le ti gbe ife ẹyẹ onigba meji fun ilẹ Germany ni saa to kọja.

Ṣugbọn eyi ti de deedee aṣeyọri meji lẹẹkan naa, pẹlu bo ṣe gba ife ẹyẹ ti idije Bundesliga ni saa to ti kọja sẹyin.

Bi a ba n sọ nipa bi Kane ṣe n fi ara si iṣẹ - ẹni to ṣe ipo kẹwaa ninu eto Ballon d'Or to kọja – ko si ẹni to ba aṣeyọri rẹ ni saa to kọja naa.

Goolu mọkanlelọgọta to gba sawọn ninu gbogbo idije ni ko sẹni to lee ba ninu gbogbo awọn agbabọọlu marun-un to wa niwaju, pẹlu bo ṣe n fi goolu mọkandinlogun la gbogbo wọn.

Koda, ipele yii lo jẹ pe oun nikan ni agbabọọlu to tun ṣi de ipele naa, lẹyin Cristiano Ronaldo toun naa gba bọọlu mọkanlelọgọta sawọn lọdun mọkanla sẹyin.

Kane ni agbabọọlu kan ṣoṣo to gba goolu sawọn julọ ninu idije Bundesliga – Bẹẹ ninu idije Champions League, goolu mẹrinla lo gba sinu awọn wọ ipele sẹmi final.

Ninu idije German Cup, Kane gba goolu mẹwaa sawọn, to fi mọ goolu mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ kan, iyẹn 'hat-trick', nibi ti wọn ti fẹyin akẹgbẹ wọn, Stuttgart gbolẹ nibi aṣekagba idije naa, bẹẹ lo tun gba goolu kan sawọn ninu idije German Super Cup.

Ko tii si agbabọọlu kan to tii gba goolu rẹpẹtẹ sawọn to Harry Kane fun Bayern, ẹgbẹ agbabọọlu to ti ni awọn agba ọjẹ bii Gerd Muller, Rummenigge ati Robert Lewandowski.

Goolu mejila ti Kane gba sawọn fun England ni saa to kọja – to fi mọ goolu mẹfa to gba wọle sinu awọn ninu idije ife ẹyẹ agbaye – lo jẹ ki apapọ goolu rẹ jẹ mẹtalelaadọrin.

Agbabọọlu kan ṣoṣo ninu itan idije ilẹ Yuroopu lo ṣi gba ọpọ goolu sawọn ninu saa kan, Lionel Messi to gba goolu mejilelọgọrin sawọn fun Barcelona ati Argentina ni saa 2011 si 2012.

Awọn miran lori ila ni Muller (72 ni 1972-73); Cristiano Ronaldo (66 ni 2011-12 ati 2014-15); agbabọọlu ọwọ iwaju tẹlẹ fun Brazil, Ronaldo (66 ni 1996-97), Erling Haaland (64 ni 2022-23) ati Luis Suarez (64 ni 2015-16).

Agbabọọlu ọwọ iwaju fun England tẹlẹ, Alan Shearer sọ fun BBC laipẹ yii wi pe: "Harry Kane lo yẹ ko gba ife ẹyẹ Ballon d'Or.

"Awọn ipa ati ifarajin rẹ lati bi oṣu mejila si mejidinlogun sẹyin jẹ eyi to wu ni lori fun Bayern, ati fun England. Fun idi eyi, oun lo yẹ ko gba a,"

Bakan naa, agbabọọlu miran fun Three Lions, Danny Murphy sọ ninu ọrọ rẹ pe: "Aisinmi ni bọọlu rẹ to n gba sawọn ba de, o si mu iwuri dani. O ti koju ọkan lara awọn saa bọọlu to dara ninu irin ajo rẹ, o si yẹ ko gba aami ẹyẹ.

"O jẹ ọlọgbọn ni Bayern Munich latigba to ti wa nibẹ, o si tete fara mọ wọn, bẹẹ lo tun dara fun ọwọ iwaju wọn lati bi oṣu mejila sẹyin."