You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A ti gba mílíọ́nù márùndínlọ́gbọ̀n Náírà owó tí Ogogo gbé fún Ìmáàmù àgbà Ilaro padà - Ẹbí Ogogo
Ni ọjọ ti wọn sin oku Ogogo, se ni ọrọ foju han , to si n ja rain nilẹ, eyi to ta ba Imaamu agba fun ilu Ilaro, Sheik Muhammad Tajudeen Mustapha Adewunmi.
Ọrọ naa si lo da lori pe gbajumọ osere tiata to di oloogbe, Taiwo Hassan Ogogo, tii se ọmọ bibi ilu Ilaro gbe owo tuulu kan fun Imaamu agba naa, ki iku to pa oju rẹ de.
Ọjọ́ Aje ti o kọja ni iroyin naa n ja ranyin lori ẹ̀rọ ayélujára nípa owó tí wọn ní Alhaji Taiwo Hassan Ogogo gbe fun Imaamu agba naa.
Níbi eto isinku Taiwo Hassan Ogogo nilu Ilaro ni iroyin naa ti kọkọ jade.
Ọkàn lara awon Agba Alfa, Sheik Iskilu Sugar ni ó tí kọkọ sọ pé ólogbe naa gbé owo toto milionu lọna mẹẹdọgbọn kalẹ fún Imam agba ilu ilaro, kí o tó dagbere faye.
Ohun ti ọpọ eeyan si n sọ ni pe owo naa wa fun kikọ mọsalasi nilu naa ni.
Ọ̀rọ̀ yii ti ta ba ile, o ti ta ba oko, eyi to si n ta ẹrẹ si orukọ rere ojisẹ Ọlọrun naa.
Mo ti da miliọnu mẹẹdọgbọn Naira owo Ogogo to gbe fun mi pada fun ẹbi rẹ - Imaamu agba Ilaro
Amọ asiri ọrọ naa lu sita nibi eto adura ọjọ mẹjọ fun oloogbe naa eyi to waye lọjọ Aje ana nilu Ilaro.
Imaamu agba fun ilu Ilaro ti wa sọrọ soke lori ọrọ naa, to si fi ọwọ gba aya pe lootọ ni oun gba owo miliọnu mẹẹdọgbọn Naira lọwọ Ogogo.
Amọ o yan pe owo naa kíi ṣe lati fi kọ mọsalasi gẹgẹ bi awọn eeyan kan se n gbe kaakiri.
O ní Alhaji Taiwo Hassan Ogogo fun oun ni owó naa lati fi kọ ile akọpati to n kọ lọwọ fun mọlẹbi rẹ nilu Ilaro amọ ti ko tii pari rẹ.
Baba Imam agba náà sọ pe owo milionu marundinlọgbọn Naira naa ni oun ti da padà fun awon ẹbi Ologbe naa lati fi pari ile akọpati fun idile Alhaji Taiwo Hassan Ogogo tí ó wà ní ilu ilaro.
Nibi ayẹyẹ naa si ni Olori ile awọn Ogogo ti kede pe lootọ ni awọn ti tẹwọgba miliọnu mẹẹdọgbọn Naira naa lọwọ Imaamu agba fun ilu Ilaro.
Igbesẹ yii si lo mu ki ọpọ eeyan maa kan saara si Imaamu agba Ilaro pe olotitọ eeyan ati ẹni to se fi ọkan tan ni.
Awọn ọmọ, aya, ẹbi ati ọrẹ peju se adura ọjọ mẹjọ fun Ogogo
Wayi o, eto adura ọjọ kẹjọ waye loni ọjọ Aje fun gbajumọ osere tiata, Oloogbe Taiwo Hassan Ogogo
BBC News Yoruba wa nilu ilaro níbi tí eto adura ọjọ kẹjọ, Fidau, naa ti n waye fún Ologbe naa.
Awọn ẹbí, ara, ọrẹ ati awon osere nidi ìṣe tiata Yoruba ni peju sibi ayẹyẹ fidau náà lati ṣe idaro ẹni wọn tí ó lọ.
Awọn gbajumọ osere tiata ati alajọsepọ oloogbe Ogogo, bii Yinka Quadri, Dele Odule, Mr Latin atawọn agbaagba osere tiata miran ti wa nibi adura naa to n waye nilu Ilaro, nipinlẹ Ogun.
Kira, ọmọ Taiwo Hassan Ogogo ati aburo rẹ, Lima, naa wa níbi eto adura fidau Baba wọn, Alhaji Taiwo Hassan Ogogo pẹlu awọn gbajumọ osere mii ti aye mọ.
Bakan naa ni Adebayo Salami ati Jide Kosoko, agba osere tiata wa nibi ayeye fidau Taiwo Hassan Ogogo.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelọlogun osu kẹjọ ọdun 2026 ni Ogogo dagbere faye tori aisan jẹjẹrẹ to mu, ti wọn si sìn oku rẹ ni ilana esin musulumi ni ile molebi rẹ tí ó wà ní ìlú ilaro ni ọjọ Aje.
Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju
Ọsẹ to kọja yii ni awọn ọmọ Ogogo meji, Kira ati Lima Taiwo, ke gbajare lori ayelujara, pe baba awọn ti ni aisan jẹjẹrẹ to ti wa ni ipele kẹrin.
Wọn fi omije rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria, pe ki wọn dide iranlọwọ nipasẹ oogun ibilẹ, to ba si ṣe ti oloyinbo to daju naa ni.
Awọn ọmọ naa sọ pe awọn dokita oyinbo ni ko fẹ tọju Ogogo mọ, lo jẹ kawọn jade beere ọna mi-in.
Wọn sọ nigba naa pe awọn ko ba tilẹ gbe e lọ si India fun itọju, amọ ilera rẹ ko gbe irinajo naa mọ.
Kira ati Lima sọ nigba naa pe awọn ko tọrọ owo o, iranlọwọ ni gbogbo ọna miran lawọn tori ẹ wa sori ayelujara.
Ko ju ọjọ meji lẹyin ikede naa, ti okiki kan pe Ogogo ti jade laye latari aisan naa, amọ irọ gbuu ni eyi pada jẹ.
Opin ọsẹ to kọja yii si ni awọn agba oṣere lagbo tiata Yoruba korajọ, ti wọn ṣe adua nilana ẹsin Islam fun Taiwo Hassan; gbajumọ oṣere tawọn eeyan mọ si Ogogo.
Ta ni Taiwo Hassan Ogogo?
Ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹwa ọdun 1959 ni wọn bi Taiwo Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo.
Ọmọbibi ilu Ilaro, to wa ni agbegbe Yewa nipinlẹ Ogun nii se, to si jẹ ibeji, tori ibeji ni wọn saba maa n bi ninu idile rẹ.
Bakan naa ni baba ati iya rẹ naa jẹ ibeji.
Ogogo pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ nile ẹkọ Christ Church nilu Ilaro, ko to morile ile ẹkọ girama Gazikia College nilu Eko.
Amọ Ogogo ko le pari ile ẹkọ girama naa tori ọda owo, lẹyin naa lo wa lọ sile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ nibi to ti kọ nipa isẹ atọkọse, ti a mọ si Mẹkaliki.
Gbajumọ osere tiata naa si sisẹ bii Mẹkaliki fun ọdun mẹtala gbako nileesẹ to n pese omi, water corporation.
Ogogo bẹrẹ isẹ tiata lọdun 1981 ni kete to bẹrẹ isẹ mẹkaliki, to si kuro lẹnu isẹ mẹkaliki nileesẹ Water Corporation lọdun 1994, ko le gbajumọ isẹ tiata to yan laayo.
Agba osere naa ti gba oniruuru ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, to si tun gba ami ẹyẹ ipa to ko ninu ere Anikulapo, tii se Alaafin Oyo.