Tírélà ló pa ọkọ mi tó jẹ́ awakọ̀ èrò, ìdá mẹ́ta ẹ̀bùn owó ló kàn mì, ìyá ọkọ mi kò bèèrè àwọn ọmọ di ìsinyìí - Opó

Tírélà ló pa ọkọ mi tó jẹ́ awakọ̀ èrò, ìdá mẹ́ta ẹ̀bùn owó ló kàn mì, ìyá ọkọ mi kò bèèrè àwọn ọmọ di ìsinyìí - Opó
Published

Yoruba lo ni n o sebi iya ko le jọ iya, n o se bi baba ko le jọ baba amọ eyi ko ri bẹẹ pẹlu awọn oku to ba ti ku, ti wọn fi ọmọ ati aya silẹ saye lọ.

Lọpọ igba ti oku ba ku, oniruuru ileri lawọn eeyan maa n se fun awọn ọmọ ati aya wọn amọ to jẹ pe ileri ori ahọn lasan ni, ti ko fidi mulẹ ni.

Oniruuru isoro ati inira, ẹsin ati ibanujẹ si ni ọpọ opo ati awọn ọmọ alainibaba maa n koju lẹyin ti baale ile wọn ba papoda.

Idi si ree ti awujọ agbaye gan se ya ọjọ kẹtalelogun osu kẹfa ọdọọdun sọtọ gẹgẹ bii ayajọ ọjọ lati se iranti awọn opo.

Lasiko ayajọ iranti awọn opo yii, BBC News Yoruba tọ awọn opo kan lọ, paapaa awọn obinrin ti n se opo ni kekere, ti wọn si ni awọn ọmọ wẹwẹ lati tọju.

A fẹ mọ ohun ti wọn n la kọja lẹyin ti ọkọ wọn papoda, bawọn ẹbi se sugba wọn si ati bo se rọrun tabi nira lati se itọju awọn ọmọ wọn.

Ajọ Alaanu Adunni Lagba Golden Age Foundation si lo ko awọn opo yii jọ lati gba wọn ni imọran fun igbe aye ifọkanbalẹ ni ayajọ ọjọ awọn opo ti Ọdun yii.

Ọkọ mi se ariya ọjọ ibi nla fun mi, n ko mọ pe o n se idagbere fun mi ni, ọsẹ keji lo bẹrẹ aisan to pa a - Temitope Taiwo

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Temitope Taiwo ni o ti pe ọdun kejila bayii ti oun ti padanu ọkọ oun.

"Ni ọdun ti ọkọ mi ku, ko si nkankan to se e ni ibẹrẹ ọdun yẹn, amọ nigba to di osu kẹjọ, o se ariya ọjọ ibi nla fun mi.

N ko mọ pe o n se idagbere fun mi ni tori lọsẹ keji lẹyin ariya naa, o sun, nigba to si maa ji, oju rẹ mejeeji ti di, ti ko si le laju mọ.

A n gbe kiri lati ile iwosan kan si omiran amọ ni aarọ kutukutu, o jẹ Ọlọrun nipe.

Se ni mo daku, nigba ti maa laju, wọn ti fi ẹrọ to n yẹ ifunpa si mi lapa, ti wọn si sọ fun mi pe Ọlọrun ti pe ọkọ mi sọdọ."

Nigba to n sọ ipa ti awọn ẹbi ọkọ rẹ ko lori itọju oun ati ọmọ rẹ, lẹyin iku ọkọ rẹ, Temitope Taiwo sọrọ, o bu sẹkun.

"Igba miran maa n wa, ti n ko ni ni owo kankan lọwọ tori bi Naijiria se ri, paapaa lasiko ti awọn ọmọ ba fẹ pada sile ẹkọ.

Ko si iranwọ nibi kankan, emi naa ni mo n ko ba oju, ko ba imu."

Lati igba ti ọkọ mi ti ku, iya ọkọ mi ko tii yọju si awọn ọmọ-ọmọ rẹ sugbọn wọn tẹwọ gba owo - Oluwatobi Ogunlade

Nigba ti oun naa n ba BBC News Yoruba sọrọ, Oluwatobi Ogunlade salaye bi ọkọ rẹ se jade laye, eyi to mu ko di opo ni ọsangangan aye rẹ.

"Onimọto ni ọkọ mi, Pansẹkẹ si Ikorodu lo n na, o gbe ero lọ, amọ nigba to n pada bọ wa sile, o ni ijamba pẹlu tirela ni Sagamu, o si ku ni ẹsẹkẹsẹ.

Awọn ẹbi rẹ wa, awọn ẹgbọn rẹ ni ki n ma lọdọ awọn, mo lọ sibẹ, mo si sun sibẹ, mo mu asọ kan lọwọ pẹlu ireti pe ma ba paa asọ nile iwosan.

Amọ nigba ti ilẹ mọ, emi ati ọmọ rẹ wẹ pe ka maa lọ sile iwosan, ni wọn ba n pa itan fun mi pe a ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni, ti wọn si ni o ti jade laye.

O jẹ nkan ibanujẹ fun mi gan, n ko si le gbagbe rẹ ninu iriri aye mi.

Oluwatobi Ogunlade wa tẹsiwaju lati sọ nipa iha ti awọn ẹbi ọkọ rẹ kọ si lẹyin iku ọkọ rẹ, eyi to ni o jẹ ohun ibanujẹ gan, ti aye ko gbọdọ maa ba oun gbọ nipa rẹ.

"Awọn onitirela to kọlu mọto ọkọ mi fẹ fun wa ni owo gba ma binu, amọ nigba ti awọn ẹgbọn ati aburo ọkọ mi yọju si agọ ọlọpaa, tori emi ko le yọju sibẹ, mo wa nile opo.

Wọn fun wọn lowo, se ni wọn fun mi ni ida kan ninu ida mẹta owo naa, wọn ko si bikita pe awọn ko mọ bi a se ra ilẹ ibi ti a sin ọkọ mi si.

Lati igba ti ọkọ mi ti ku, iya ọkọ mi ko tii yọju si awọn ọmọ-ọmọ rẹ titi di akoko yii, sugbọn wọn tẹwọ gba owo."

Ogunlade wa fi ọwọ gbaya pe erongba oun ni lati di obinrin to dantọ

Igba ti ọkọ mi ti n se aisan, ni mo ti ri ọwọ ti iya ọkọ mi n gbe, ti mo si n ro pe, se kii se pe iya fẹ jẹ ọta mi - Opeyemi Sanyaolu

Ẹ wa ara yin rin, ẹ maa se ohun tuntun, ẹ gbe igbesẹ tuntun, ẹ sọrọ jade, ki a le ri iranlọwọ ti a maa se fun yin - ajọ alaanu Adunni Lagba Golden Age Foundation sọ fun awọn opo

Nigba to n gba awọn opo ni imọran fun igbe aye rere, ajọ alaanu Adunni Lagba Golden Age Foundation ti Kehinde Adelaja soju fun, rọ wọn lati maa se bi wọn ti mọ bii Ẹlẹwa Sapon.

O ran wọn leti pe awọn kọ ni yoo jẹ opo akọkọ, awọn si kọ lo maa jẹ igbẹyin amọ ki wn duro sori ẹsẹ wọn, ki wọn si wa ara wọn.

"Ẹ wa ara yin rin, ẹ maa se ohun tuntun, ẹ gbe igbesẹ tuntun, ẹ sọrọ jade, ki a le ri iranlọwọ ti a maa se fun yin."