Lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún, ilé ẹjọ́ kéde olórí ikọ̀ gàńfé bí ẹni tó jẹ̀bi ẹ̀sùn ikú Tupac Shakur

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile ẹjọ kan ti dajọ pe olori ikọ awọn ọmọ ganfe kan Duane "Keffe D" Davis jẹbi pe o lọwọ ninu bi wọn ṣe ṣekupa olorin takasufee nni, Tupac Shakur.

Idajọ akọkọ to n waye ree lori iku Tupac lẹyin ọgbọn ọdun ti olorin naa ti jade laye.

Adajọ ni Davis jẹbi ẹsun ipaniyan pẹlu lilo ohun ija oloro nibi ti wọn ti yibọn pa Tupac ni Las Vegas lọjọ Keje, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1996.

Davis, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, sọ pe oun maa pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ naa.

Lasiko ti igbẹjọ n waye ni wọn ṣagbekalẹ ohun ọlọpaa kan ti wọn ka silẹ lasiko to n ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Davis lọdun 2008 nibi to ti sọ pe inu ọkọ kan ni oun wa nibi ti wọn ti yinbọn pa Tupac amọ ko sọ pe oun ni oun yinbọn naa.

Ẹni ọdun marundinlọgbọn ni Tupac, to n si ṣe daadaa nidii iṣẹ orin to yan laayo ki wọn to ṣekupa a lọdun 1996 to si ti ta awo orin to le ni miliọnu marundinlọgọrin.

Awọn olupẹjọ sọ fun ile ẹjọ pe bi o tilẹ jẹ pe Davis kọ lo yinbọn pa Tupac funra rẹ, oun lo ṣe atọna bi wọn ṣe pa olorin naa ati pe oun lo fun ibatan rẹ, Orlando Anderson ni ibọn ti wọn fi pa Tupac.

Davis ni olori tẹlẹ fun awọn ọmọ ganfe South Side Compton Crips.

Wọn sọ fun ile ẹjọ Davis ṣeto ipaniyan naa na ṣe ti ẹ ki emi naa ṣe temi lẹyin ti Anderson ati awọn ọmọ ẹyin Tupac ja tan ni Las Vegas ṣaaju ki yinyin ibọn pa ara ẹni naa to waye.

Asiko ti ifanfa nla n waye laaarin awọn olorin takasufee East Coast ati West Coast ati igba ti ija n waye laaarin awọn ọmọ ganfe Bloods ati Crips eyi to niiṣe pẹlu awọn olorin takasufee asiko igba naa.

Awọn ẹbi Tupac naa wa nile ẹjọ ti wọn si fi idunnu wọn ham lori idajọ naa bi ẹgbọn Tupac ṣe dimọ olupẹjọ leyin idajọ naa, tawọn si n sunkun.

Bakan naa ni awọn ololufẹ Tupac tun kan saara si idajọ ọhun bi awọn kan ṣe n sunkun ni ita ile ẹjọ.

Bi igbẹjọ naa ṣe lojutu u ko ṣẹyin bi Davis ṣe fi ẹnu ara rẹ sọ pe oun wa ninu Cadillac funfun ti wọn ti yinbọn pa Tupac.

Bakan naa lo ti ṣaaju sọ fun awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuye lọdun 2008 pe ọwọ oun wa ninu iku Tupac nigba ti wọn lọ bii leere nipa iku olorin takasufee mii, Notorious B.I.G.

Davis tun ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa rẹ ninu iwe to kọ lọdun 2019 to pe ni Compton Street Legend.

Amọ iwe naa atawọn ifọrọwanilẹnuwo to ṣe lẹyin iwe naa lo tu gbogbo adehun aabo ti oun atawọn alaṣẹ jọ fẹnuko le lori lati ma koju igbẹjọ lori aw.on iwa ọdaran, ti ile ẹjọ si ni wọn le lo awọn ifọrọwanilẹnuwo to ṣe tako o.

Olupẹjọ fun ijọba, Binu Pala sọ fun awọn adajọ pe ki wọn gba gbogbo ohun ti Davis sọ gbọ, ki wọn si dajọ pe o jẹbi ẹsun ipaniyan.

Fun ọpọ ọdun ni Davis ti maa n sọ fawọn eeyan pe oun lọwọ ninu iku Tupac Shakur, ninu awọn akọọlẹ rẹ, awọn ifọrọwanilẹnuwo to ṣe ati ohun to sọ fun ọlọpaa.

Palal sọ fun ile ẹjọ pe ohun gan lo paṣẹ pe ki won pa Tupac.

Awọn agbẹjọro Davis sọ fun ile ẹjo pe irọ lasan ni gbogbo awọn nnkan ti Davis n sọ kiri tẹlẹ, pe ọgbọn lati tẹ iwe rẹ, ko fi le ri ow oni.

Agbẹjọro rẹ, Michael Sanft sọ fun awọn adajọ pe pe ki wọn ma gbọ si onibaara oun lẹnu, pe irọ lasan lo n pa ati pe ko si ẹri lati fidi rẹ mulẹ pe o lọwọ ninu iku Tupac Shakur.

Amọ adajọ ti wa fidi rẹ mulẹ bayii pe Davis jẹbi ẹsun pe o lọwọ ninu iku Tupac.

Adajọ ile ẹjọ ẹkun Clark County, Carli Kierny ti wa mu ọjọ Kẹtala, oṣu Kẹwaa gẹgẹ bi ọjọ ti wọn maa dajọ naa.

Adajọ naa tun sọ pe Davis le pe ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin ti wọn ba da ẹjọ rẹ tan.

Ta ni Tupac Shakur?

Tupac Shakur jẹ olorin takasufee ilẹ Amẹrika ti wọn ni ọdun 1996.

2pac Shakur tabi Makaveli ni orukọ ti awọn eeyan mọọmọ nigba aye rẹ.

Ni ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa ọdun 1971 ni wọn bi ti wọn si ṣekupa a ni ọjọ Kẹtala, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1996.

Parish Lesane Crooks ni orukọ ti iya rẹ sọ ọ nigba ti wọn bii ki iya rẹ to yi orukọ naa pada si Tupac Amaru Shakur lẹyin bii ọdun kan ti wọn bii tan.

Tupac lo oṣu mẹjọ lẹwọn fun ẹsun ifipabanilopọ laaarin ọdun 1994 si 1995.