You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀fọ̀ tún ṣẹ̀ lágbo tíátà, àrùn jẹjẹrẹ tún pa gbajúmọ̀ òṣèré míràn, Atinuke Kareem
Iroyin ibanujẹ miran lo tun ti sọ lagboole awọn oṣere tiata nilẹ Naijiria bayii, pẹlu bi gbajumọ oṣerebinrin nni, Atinuke Kareem ṣe jade laye.
Ko si nnkan meji ti a gbọ pe o ṣokunfa iku Atinuke Kareem, to kọja aisan jẹjẹrẹ ti ọmu.
Gomina ẹgbẹ oṣere, ẹka ti TAMPAN nipinlẹ Ogun, owolabi Ajasa lo fidi iroyin yii mulẹ loju opo ayelujara rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.
Ajasa sọ pe ibanujẹ ni iku oṣerebinrin naa, Kareem jẹ fun wọn, pẹlu bi aisan jẹjẹrẹ ti ọmu ṣe da ẹmi rẹ legbodo.
Yatọ si Owolabi Ajasa to fidi rẹ mulẹ, aarẹ ẹgbẹ oṣere TAMPAN, Bolaji Amusan tọpọ awọn eeyan mọ si Mista Latin naa tun fidi rẹ mulẹ.
Iṣẹlẹ yii ni yoo jẹ eyi ti yoo iṣẹlẹ kẹta laaarin oṣu meji, ti aisan jẹjẹrẹ yoo maa ran awọn oṣere tiata lọ sọrun lai ro tẹlẹ.
Tope Osoba ni iroyin rẹ kọkọ gba igboro lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026; ko ju bi ọsẹ meji aabọ lọ, ti Taiwo Hassan Ogogo naa tun jade laye lori aisan jẹjẹrẹ yii.
"Pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú ati adura wa, Atinuke jade laye, o si ti dahun ipe ikẹyin"
Nigba to n kede, Owolabi Ajasa sọ pe "A dupẹ lọwọ gbogbo eeyan ti wọn dide iranlọwọ nipa owo, adura ati amọran, pẹlu igbaruku ti si itọju ọkan lara wa, Atinuke Remilekun Kareem.
"Ifẹ yin ati akitiyan yin lasiko ipenija rẹ jẹ ohun pataki si wa ati mọlẹbi rẹ. A fi tọkantọkan dupẹ.
"O ṣeni laanu wi pe, pẹlu ibanujẹ wi pe gbogbo igbiyanju ati adura wa, Atinuke jade laye, o si ti dahun ipe ikẹyin," Ajasa sọ bẹẹ.
Bakan naa lo ni awọn ko le ba Ọlọrun wijọ lori oṣere naa, ati pe adura nikan ni awọn le gba wi pe ki Ọlọrun tẹ e si afẹfẹ rere, ko si fun awọn ẹbi oloogbe ni ọkan lati farada ipapoda ọhun.
"Àìsan jẹjẹrẹ ọmú ló pa á"
Nigba toun naa n kede, Bolaji Amusan sọ pe aisan jẹjẹrẹ lo ṣeku pa Atinuke Kareem, lẹyin ọpọlọpọ itọju.
"Aisan jẹjẹrẹ lo gba a kuro lọwọ wa, to si fi awọn itan ti a ko le gbagbe silẹ ninu ọkan wa. Sun re o. Atinuke Kareem.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni obinrin naa jade sori ayelujara lati bẹbẹ fun iranlọwọ owo ati itọju lori aisan jẹjẹrẹ ọmu to n ba a finra.
Kareem sọ ọ di mimọ pe oun na ọpọlọpọ, ti awọn mọlẹbi oun naa si tun ti na owo pẹlu lati fi tọju oun.
O ni agbara ti ko gbe e mọ, lo jẹ koun jade lati tọrọ fun iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu.
Bakan naa lo sọ pe ko wun oun lati fi aye silẹ bayii, paapaa nitori awọn ọmọ meji ti wọn ṣi kere, ati pe ko sẹni to le tọju wọn bi oun.