NCDC buwọ́lu N100,000 náírà ọ̀sẹ̀-ọ̀sẹ̀ fún àwọn tó ti lùgbàdì ààrun Ebola ní Nàíjíríà

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun nilẹ Naijiria, NCDC ti sọ pe ohun ti buwọ lu ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira fun gbogbo awọn alaisan arun Ebola lọsẹ-ọsẹ.

NCDC sọ pe gbogbo awọn to n gba itọju arun Ebola patapata ni wọn yoo fi owo naa ṣe iranwọ fun, lojuna lati dena itankalẹ rẹ ni FCT.

Alakoso agba ajọ NCDC, Jide Idris lo fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Aiku to kọja, to si ṣalaye pe awọn gbe iranwọ naa dide lati rọ ajaga iṣuna awọn to n gba itọju naa silẹ fun wọn.

Gẹgẹ bi Idris ṣe ṣalaye ninu ọrọ rẹ, o ni pupọ ninu awọn to wa labẹ ayẹwo itọju arun Ebola, ni wọn n sọ pe owo ounjẹ, ile gbigbe ati itọju awọn mọlẹbi wọn ti n kọja agbara awọn.

O ni awọn eeyan naa n sọ pe nnkan ko faramọ fun awọn lati gbọ bukata ile wọn, pẹlu bi wọn ṣe n gbiyanju lati tẹle ilana awọn alakoso, lati dena itankalẹ arun Ebola.

Idris ni awọn aniyan ti awọn eeyan naa n ṣe, jẹ ohun ti wọn ṣagbeyẹwo rẹ, to si lawọn rii pe awọn eeyan naa nilo iranlọwọ to yẹ, lasiko ti wọn fi n tẹle ilana awọn alakoso.

"A maa san owo fun ibi ti wọn n gbe; a maa san owo ounjẹ wọn. Awọn kan n beere fun owo iranlọwọ lati maa fi bọ mọlẹbi wọn," Idris sọ bẹẹ.

"NCDC ti buwọ́lu owó ìrànwọ́ náà"

Ọga agba naa ti wa jẹ ko di mimọ pe ajọ NCDC ti buwọlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan fun ẹnikọọkan to wa labẹ eto ayẹwo, lati le fi mu irọrun ba igbe aye wọn.

"A ma maa fun ẹnikọọkan ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira lọsẹ-ọsẹ fun igbe aye idẹrun ati ounjẹ fun wọn, nitori pe wọn n kọminu," Idris sọ bẹẹ.

O tun ṣalaye pe iranlọwọ naa ko si lara agbekalẹ tatie to ajọ NCDC, ṣugbọn to ṣe pataki lati ṣe, nigba ti awọn eeyan naa ti bẹrẹ sii sọrọ jade nipa adojukọ wọn labẹ ilana eto ayẹwo awọn alakoso.

"Eyi ko si lara igbesẹ ti a ti la kalẹ, ṣugbọn o jẹ pajawiri. A ma maa ṣatungbeyẹwo rẹ bi nnkan ba ṣe n lọ siwaju sii," o sọ bẹẹ.

Idris jẹ ko di mimọ pe bi gbogbo igba ni awọn yoo maa ṣagbeyẹwo eto ọhun bi idaagbasoke ba ṣe n de, to si tun fi kun ọrọ rẹ pe ajọ naa yoo maa dide iranlọwọ lojuna bi eto naa ba ṣe n lọ.

Bakan naa lo rọ awọn eeyan kaakiri Naijiria lati wa ni imurasilẹ, to si ni ojuṣe gbogbo ileeṣẹ eleto ilera ni, ki wọn ma ṣe duro de awọn alakoso FCT ki wọn too gbe igbesẹ.

"Eyi kii ṣe ojuṣe FCT nikan. Ohun ti a ni lati ṣe fun FCT, a tun ni lati ṣee fun ipinlẹ miran," o sọ bẹẹ.

"Àwọn gómìnà ní láti dìde sọ́rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí"

Siwaju sii ni alakoso agba ajọ NCDC naa tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn alakoso ijọba ipinlẹ ni lati pese awọn iranlọwọ to ba yẹ, lati le bẹrẹ sii tọpinpin awọn to ba ti ni arun naa.

Idris ni ki wọn pese iranlọwọ owo ati ohun elo lati fi ṣatilẹyin fun titọpinpin, ki awọn eeyan pamọ fun ayẹwo ati awọn nnkan miran ti wọn nilo lati fi dena itankalẹ.

O ni igbaradi lati tete koju arun naa ko to di pe o gbilẹ ṣe pataki pupọ lati dena itankalẹ.

Igbesẹ iranlọwọ yii lo waye lẹyin ti wọn fidi rẹ mulẹ pe ẹnikan ti ko arun Ebola wọ Naijiria lati Abuja logunjọ, oṣu Kẹwaa.