Àwọn ọ̀nà tí mà á gbà láti fi kó àwọn agbèrò kúrò lọ́nà rèé tí mo bá di gómìnà Eko - Funsho Doherty

Funsho Doherty wọ aṣọ olomi aro ati pupa ti wọn kọ orukọ rẹ si lara , gbohun wa niwaju rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oludije sipo gomina ipinlẹ Eko lẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, NDC, Funsho Doherty ti rọ awọn eeyan ipinlẹ lati ma dibo fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nibi eto idibo to n bọ lọna.

Doherty parọwa yii nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori erongba rẹ lati di gomina Eko.

O sọ pe idi ti oun fi parọwa yii ko ṣẹyin pe awọn eeyan ipinlẹ Eko ko maa jẹ anfaani ijọba to bo ṣe yẹ to si ni gbogbo awọn ohun amayedẹrun ti eeyan fi maa jẹ mukundun ijọba awaarawa ni ko si ni ipinlẹ Eko.

"Ta ba wo gbogbo nnkan to jẹ ti anfaani ara ilu a maa ri pe wọn o ni.

"Ta ba wo eto ẹkọ, ta ba wo eto ilera, ta ba wo eto ọkọ ero, gbogbo awọn eto yii, eyi to jẹ nnkan to ṣe pataki fun ara ilu, fun abiyamọ ati ọmọ,a ri wi pe eto to yẹ ki ijọba ṣe, owo to yẹ ki ijọba na sawọn nnkan yẹn araalu o ri anfaani yẹn."

"Ibugbe ẹgbẹrun lọna ọgbọn ni maa kọkọ kọ laaarin ọdun akọkọ ti mo ba di gomina"

Nigba to n sọrọ lori erongba rẹ lati kọ ile igbe to to ẹgbẹrun aadọjọ laaarin ọdun mẹrin to ba fi wa nipo to ba di gomina Eko, Doherty sọ pe kii ṣe laaarin ọdun kan ni awọn maa kọ ile naa.

O ṣalaye pe ibugbe ẹgbẹrun lọna ọgbọn ni afojusun ti awọn maa kọkọ kọ laaarin ọdun akọkọ ti awọn yoo si maa kọ kun un bi eto naa ba ṣe n lọ.

O fi kun pe oriṣiriṣi eto ni awọn ti la kalẹ lati fi ri pe eyi wa si imuṣẹ, ki o si le jẹ irọrun fun awọn to maa gba ile naa.

"A ma ṣe ko rọrun fun awọn ti o maa gba ile yẹn lati ri owo lati ya lati ra ile lati fi kun owo ti awọn ni to si jẹ pe awọn kan ninu ile yẹn a o ni ta wọn, a ma fi ṣe ile ti wọn maa ya gbe ni."

Lori awọn agbegbe ti wọn maa kọ awọn ile naa si, Doherty sọ pe awọn agbegbe bii Ikorodu, Badagry, Epe ati Ibeju Lekki ni wọn n foju sun lati wa ilẹ si nitori ko si ilẹ laaarin igboro, ti wọn si le wo ile lati fi kọ ile.

"Sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ maa dinku ti a ba gbe ilana to tọ kalẹ"

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lori awọn ọna ti sunkẹrẹ fakẹrẹ maa n da laamu, oludije sipo gomina naa ṣalaye pe awọn maa ṣamojuto eto irinna paapaa nipa rira awọn ọkọ ero to maa ki lilọ bibọ rọrun fawọn araalu.

O sọ pe awọn nnkan to maa n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ko ṣẹyin awọn ọna to maa n bajẹ ni ko ni ri atunṣe bọrọ ati bi awọn ọlọkọ ero ṣe maa n duro lawọn oju popo lai si amojuto to peye fun.

"Ta ba jẹ ki eto wa lori awọn ilana wa lori gbogbo awọn kini ti a n sọ yii, ta ṣe eto ọkọ ero to duro ire, ẹ ẹ ri ilọsiwaju maa wa."

O ṣalaye pe awọn ọkọ naa maa dabi ti BRT amọ awọn ko ni pese ọna mii, to si jẹ pe awọn ọna BRT naa ni awọn ọkọ naa yoo maa lo ti awọn si maa ra awọn ọkọ ero kun eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ.

Bakan naa lo sọrọ nipa pipese awọn ọna oju irin lojuna ati mu adinku ba awọn sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ dani.

Nigba to n sọrọ lori ọrọ awọn agbero, o ni ohun gbagbọ pe awọn to n ṣe iṣẹ n wa owo ti wọn fi maa jeun ni to si jẹ pe ọpọlọpọ wọn lo maa ṣe iṣẹ mii ti ijọba ba pese rẹ fun wọn.

Doherty woye pe ijọba lo n fun awọn agbero lati maa hu awọn iwa ko tọ ti wọn n hu nigboro nitori wọn maa n lo wọn lati huwa ipa lasiko ibo, to si ni gbogbo awọn eyi loun maa fopin si ti oun ba di gomina.