Níbo ni N10b nairà, owó ìrànwọ́ láti kojú àrùn Ebola tí Ààrẹ Tinubu kéde nínú oṣù Kẹfà wà?

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook Bola Tinubu/Facebook
Oludije sipo aarẹ ilẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC, Atiku Abubakar ti sọ pe ki ijọba apapọ ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun gbogbo araalu nipa ohun ti wọn fi biliọnu mẹwaa naira ti wọn pe lowo iranwọ Ebola ṣe.
Atiku Abubakar sọ pe ki ijọba apapọ sọ boya ijọba apapọ ti gbe owo naa silẹ, tabi pe bi owo naa yoo ṣe rin in.
Oludije naa to tun ti figba kan ri jẹ igbakeji aarẹ lo sọrọ yii ninu atẹjade to fi soju opo 'X' rẹ laipẹ yii.
Ṣaaju asiko naa, igbimọ olupolongo ibo fun aarẹ fẹgbẹ oṣelu APC lo fi atẹjade sita wi pe ko tii sẹni to fọwọ kan biliọnu mẹwaa naira ti Aarẹ Bola Tinubu kede rẹ gẹgẹ bi owo iranwọ pajawiri fun arun Ebola ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Igbimọ ipolongo naa sọ pe owo ọhun ṣi wa nibi to wa latigba naa, ko si tii sẹni to fọwọ kan an.
Ṣugbọn ṣa, Atiku nigba to n sọrọ ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin fun igbimọ ipolongo Aarẹ lẹgbẹ oṣelu ADC, Phrank Shaibu buwọlu, sọ pe ki ijọba apapọ fi ẹkunrẹrẹ nipa owo naa sita.
"Njẹ wọn ti gbe owo naa kalẹ abi bẹẹ kọ? Bi wọn ba ti gbe owo naa kalẹ, talo n ṣakoso rẹ, ati pe ki lo de ti wọn ko tii bẹrẹ sii lo gẹgẹ bi Aarẹ Tinubu ṣe kede?" atẹjade ọhun beere bẹẹ.
Bakan naa ni Atiku tun sọ pe ki ijọba apapọ ṣafihan igba ti owo naa jade, ọjọ to jade, iṣẹ ti wọn gbe jade, awọn to jẹ anfaani ati ọja ti wọn ra, to si ni o yẹ ki ijọba le ṣalaye owo, kii ṣe lati duro lori atẹjade nikan.
Níbo lowó ọ̀hún wà?
Igbimọ olupolongo ẹgbẹ oṣelu APC lọ sọ pe owo iranwọ biliọnu mẹwaa naira to wa lati koju arun Ebola ni wọn ko tii fọwọ kan rara, nigba ti ajọ to n gbogun ti itankalẹ ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC ati FAAN n lo awọn owo to wa larọwọto wọn lati koju Ebola.
Igbimọ naa fẹsun kan Atiku nipa bibu ẹnu atẹ lu eto ilera araalu, ati ọna ti ijọba n gba lati mu ọrọ Ebola ti wọn ṣawari rẹ l'Abuja.
Yatọ si owo ọhun, Atiku tun beere nipa igba ati akoko ti ijọba dide sọrọ Ebola naa to tun ṣẹṣẹ wọle.
Bakan naa lo tun sọ pe ki ni ijọba n wo nigba ti ẹni to gbe arun naa wọle, ati igbesẹ wọn lati mọ boya awọn mẹrinlelogoji naa ni alaisan naa ni ibaṣepọ pẹlu, pẹlu bi wọn ṣe lo ti lọ sile iwosan kan tẹlẹ, ko to di pe wọn lọ fi pamọ fun itọju.
Atiku wa pe fun aabo to pe ye, ati ohun elo igbalode f'awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn n dena arun ọhun, ati bi wọn ṣe n tọpinpin lati ṣawari awọn yooku to ti lugbadi arun naa.
"Awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn n tọju awọn alaisan, ti wọn si n wa awọn miran nilo aabo to pe ye, irinṣẹ ati ohun elo ni wọn nilo lati gbe igbesẹ pajawiri. Bi beere ibeere lọwọ ijọba ko tunmọ si sisọrọ abuku si wọn.
"Lati maa patẹwọ fun Aarẹ Tinubu nigba to kọ lati ṣalaye owo iranwọ pajawiri ti wọn ko tii fọwọ kan jẹ ohun abuku fawọn ọmọ Naijiria," o sọ bẹẹ.


























