'Ìgbà tí mo fi ọwọ́ kan itan mi tí mo rí ẹ̀jẹ̀ ni mo tó mọ̀ pé ọta àṣìta ìbọn ti bà mí' Broda Shaggi, ṣàlàyé ohun tó mú kó di àwátì lórí afẹ́fẹ́

Oríṣun àwòrán, Broda Shaggi
Oṣere tiata ati adẹrinpoṣonu nni, Samuel Perry, ti ọpọ mọ si Broda Shaggi ti tu pẹrẹpẹrẹ bi aṣita ibọn ṣe ba a, eyii to mu ko ma le e ṣe iṣẹ kankan fun ọpọlọpọ oṣu.
Shaggi ni iṣẹlẹ naa mu ki ẹru ba oun nipa ọjọ ọla oun nigba ti oun wo o pe o ṣeeṣe ki awọn ololufẹ oun gbagbe oun latari bi wọn ko ṣe ri oun.
Ninu fidio kan to fi lede loju opo YouTube rẹ lo ti fi ẹkunrẹrẹ ohun to waye lede nipa iṣẹlẹ naa.
Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ gbode ninu oṣu Kẹta, ọdun 2026 yii pe ọta ibọn ba oṣere naa labẹ afara Sango-Ota, nipinlẹ Ogun.
Bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa ṣokunkun lasiko naa ti awọn kan tilẹ n sọ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan, ẹnikan ti ko fẹ ki awọn akọroyin fi orukọ oun lede fidi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin Punch lasiko naa pe ọta ibọn lo ṣeṣi ba a nibi ti wọn ti n ya ere.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Oluseyi Babaseyi sọ lasiko naa pe oun ko le fidi rẹ mulẹ boya ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ naa ti waye lasiko, o si rọ awọn araalu ki wọn ṣọra fun gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kiri.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Oríṣun àwòrán, Brother Shaggi
Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, Shaggi sọ pe iṣẹ ipolowo ọja fun ileeṣẹ kan loun lọ ṣe ki ọta aṣita ibọn to ba oun.
O ni ẹru ba oun gidi lọjọ naa nigba ti oun ri ti ẹjẹ n ṣan lara oun.
Brother Shaggi ni "Ọjọ naa da bii awọn ọjọ mii gẹgẹ bi mọ ṣe maa n jade fun ipolowo ọja awọn ileeṣẹ ni, titi di igba ti Satani pinnu lati yọju.
"A ti pari eto naa, a si ti n pada sile, koda, a ti wa loju ọna marosẹ, sunkẹrẹ fakẹrẹ wa nibẹ nitori ero pọ.
"Lojiji ni mo ṣadede gbọ iro nnkan to dun, gbogbo ibi wa dakẹ rọrọ; mo ri awọn eeyan ti wọn n rin nita ti wọn si n sọrọ amọ mi o gbọ nnkan ti wọn n sọ.
"Nigba naa ni mo fọwọ kan itan mi ti mo si ri ẹjẹ nibẹ, igba naa ni mo to mọ pe ọta aṣita ibọn ti ba mi."
Shaggi sọ pe "Mi o mọ ibi ti mo wa titi ti mo fi de ile iwosan, nitori mi o tilẹ mọ bi a ṣe de ile iwosan naa. Amọ ohun kan ti mo ranti ni pe mo n gbadura titi ti a fi dele iwosan naa.
"Oriṣiriṣi nnkan lo ṣẹlẹ lọjọ naa, aagun bo mi. Mo di ẹsẹ mi mu, ṣe ẹ mọ. Mo ri ẹjẹ, mo si n duro ki dokita kan tabi nọọsi sọ fun mi pe Samuel, ma foya, aburu ko ni ṣe ẹ."
Adẹrinpoṣonu naa sọ pe ẹru ba oun pe o ṣeeṣe ki oun ma le ṣiṣẹ mọ, paapaa bo ṣe maa n jo lori itage ati ninu ere.
Ki lo ṣẹ nile iwosan?

Oríṣun àwòrán, YouTube/Brother Shaggi
O ṣalaye pe ibẹru gba ọkan oun pe awọn eeyan le gbagbe oun latari bi wọn ko ṣe ri oun mọ ninu ere.
Ninu alaye rẹ, asiko to wa nile iwosan lo fi n kọ itan to si bẹrẹ awọn ere kan loju opo YouTube, bo tilẹ jẹ pe ẹru ba a nipa ọjọ iwaju rẹ.
O sọ pe "Lawọn igba mii ti mo ba wo fidio awọn akẹgbẹ mi, mo kan maa n rẹrin ni, nigba mi ẹwẹ, niṣe ni mo maa n sunkun nitori mo maa n wo o pe o ṣeṣe ki ma n le ṣe awọn ohun ti wọn n ṣe yẹn mọ."
Shaggi ṣe iṣẹ abe ni Naijiria ko to tun lọ fun itọju mii ni Dubai.
Nigba to n sọrọ siwaju lori iṣẹlẹ naa, Shaggi sọ pe inu oun dun pe ọta naa ko ba awọn ẹya ara to le gba ẹmi oun.
O ni "Asita ibọn ni, o ba mi ni itan… to ba jẹ ibomii lo gba wa to si ba ori mi tabi awọn ibomii to ṣe koko lara mi nkọ?"
"Mo ṣi n fi ọpa rin lọwọ yii"
Nigba to n sọrọ lori ibi ti itọju rẹ de, o ni "Mo ṣi n fi ọpa rin lọwọ yii. Amọ akoko igba kan wa ti mi o tilẹ le rin rara lai lo ọpa. Mi o le gbe ẹsẹ mi silẹ… ṣugbọn mo ti le rin bayii, mo ti le duro lai si ọpa.
"Inu mi dun pe mo ni anfani lati wa laaye lẹẹkan si.
"O yẹ ki inu yin naa dun pe ẹ o tun maa ri Shaggi nitori bayii mo ni awọn iṣẹ kan to ta ẹnu to n bọ lọna."
O pari ọrọ rẹ si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn maa reti ipadabọ Abija oun laipẹ.

























