Ohun tí Mimiko, Seyi Makinde àtàwọn èèkàn míì sọ nípa Pa Fasoranti tó di olóògbé

Aworan Baba Rueben Fasoranti
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Awọn eeyan jankan jankan nipinlẹ Ondo atiawọn ipinlẹ ilẹ kaaro oojiire mii lo ti ṣabẹwo si ile Aarẹ ẹgbẹ Afenifere, Pa Reuben Fasoranti to di oloogbe lẹni ọgọrun ọdun ni ọjọ Isegun, ogunjọ oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.

Lara awọn to ṣabẹwo si awọn ẹbi baba Reuben Fasoranti ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde; gomina ipinlẹ nigba kan ri, Olusegun Mimiko; Deji Ilu Akure, Oba Aladetoyinbo; Ogunlade Aladelusi, Imaamu agba Ilu Akure, Yayi Akorede; Sẹnetẹ to ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ondo tẹlẹri; Ayo Akintẹlurẹ atawọn lorukọ lorukọ miran.

Bakan naa ni awọn ọmọ bibi ilu Akure ya bo ile baba naa pẹlu ilu ati ijo lati ṣe ayẹsi rẹ.

Baba ni itẹlọrun, wọn si ni iwa rere nigba aye wọn – Makinde, Mimiko

Seyi Makinde nile Fasoranti

Gomina Seyi Makinde to kọwọrin pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Allied People Movement (APM) ati ẹni to n du ipo igbakeji Aarẹ ninu ẹgbẹ naa, Lawal Daura ṣalaye pe dandan ni lati ṣabewo si ile baba Fasoranti nitori pe ọmọ baba ni oun jẹ.

Makinde sọ pe, bo tilẹ jẹ pe Pa Fasoranti ko ni owo bi awọn oloṣẹlu asiko yii, naa ti fi ipa rere lelẹ eyi to yẹ ki gbogbo oloṣelu maa tọ, nitoripe baba fi gbogbo ọjọ aye rẹ sin awọn ara ilu.

Makinde ṣalaye pe ọpọ oloṣelu lasiko igba baba Fasoranti ni wọn ko hu iwa to dara, sugbọn oloogbe naa ya ara rẹ sọtọ laarin wọn, ti iwa irẹlẹ baba naa si gbọdọ jẹ awokọṣe fun gbogbo oloṣelu asiko yii.

Ninu ọrọ rẹ, gomina tẹlẹri nipinlẹ Ondo, Olusegun Mimiko ṣalaye pe baba Fasoranti maa n sọ fun awọn pe wiwa nipo kii ṣe lati ko owo ilu sapo, ṣugbọn o jẹ lati sin awọn ara ilu.

Olusegun Mimiko nile Fasoranti

Mimiko sọ pe baba jẹ ẹni to fẹran adura, to si sin Ọlọrun titi to fi dagbere faye.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O tun ṣapejuwe baba naa gẹgẹ bii ẹni to ni itẹlọrun pẹlu ohun to ni, ti imura oloogbe ọhun ati bi ayika ilẹ rẹ ṣe ri ṣafihan iwa itẹlọrun rẹ.

Mimiko wa rọ awọn olosẹlu lati kọ ẹkọ lara oloogbe naa.

Imaamu agba ilu Akure Yayi Akorede banujẹ gigigidi lori ipapoda baba bo tilẹ jẹ pe oloogbe naa pe ẹni ọgọrun ọdun ko to papoda, Akorede sọ pe idi ti inu oun fi bajẹ ni pe ko si agba miran niluu Akure ati nipinlẹ Ondo to le di alafo ti baba fi silẹ.

Akorede ṣalaye pe baba naa ni gbogbo wọn n lọ sa ba ti nnkan ba n ru wọn loju, ti yoo si wa ojutu si gbogbo iṣoro ti wọn ba gbe lọ iwaju rẹ, sugbọn ni bayi, ko si agba to le ṣe ohun ti baba Fasoranti se nigba aye rẹ.

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre ti Balogun Sehinde Arogbofa ṣaaju wọn ṣalaye pe Baba Fasranti di ẹgbẹ naa mu to si ri daju pe wọn ja fun ilẹ Yoruba.

Wọn salaye pe inu iyapa ni ẹgbẹ naa wa lasiko ti Baba Fasoranti gba isakoso ẹgbẹ rẹ to si ri daju pe o mu iṣọkan wọ ẹgbẹ naa, lati ri daju pe gbogbo wọn pada di ọkan labẹ isakoso kan

Arogbofa ni Fasoranti ri daju pe ko si ẹgbẹ ẹya miran to le fori gbari pẹlu ẹgbẹ Afenifere nitoripe baba naa dari ẹgbẹ ọhun pẹlu inu kan ati otitọ.

O sọ pe ko si ẹni to le di alaafo ti baba yii fi silẹ ninu ẹgbẹ Afenifere.

Ọrọ mọlẹbi Fasoranti

Ọmọ baba naa, Funmilayo Fasoranti to n wa pẹlu rẹ ni gbogbo igba sọ fun BBC Yoruba pe bo tilẹ jẹ pe baba ti dagba ko wu awọn ki baba lọ notoripe titi di igba ikẹyin rẹ lo ṣi n fun gbogbo ọmọ rẹ ni amọran to yẹ.

Funmilayo sọ pe baba jẹ olufẹ ẹkọ to yanranti, idi niyi to fi da ile ẹkọ silẹ, to si ri daju pe gbogbo ọmọ rẹ lo ni ẹkọ to yanranti.

Ọmọ baba salaye pe, baba fẹran ibawi, bo tilẹ jẹ pe ohun jẹjẹ ni baba yoo fi sọ, ṣugbọn o ri daju pe o gbin iwa rere sinu gbogbo ọmọ nipa ibawi ati imoran.

Funmilayo pari ọrọ rẹ pe baba rere ni baba oun, ati pe ti oun ba pada wa saye ọdọ baba Fasoranti no oun tun ma pada si gẹgẹ bii ọmọ.

"Mo rí ìjọba amúnisìn, mo rí ìgbòmìnira, mo rí ogun àti àlááfíà. Nínú gbogbo rẹ̀, ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni mo dì mú" - Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Reuben Fasoranti olórí ẹgbẹ́ Afẹnifẹre tó jáde láyé

Ọdun 1926 ni wọn bi Baba Fashọranti ni ilu Uso ni ipinlẹ Ondo. Iṣẹ olukọ lo ti kọkọ bẹrẹ ki o to darapọ mọ oṣelu ati ijangbara fun iṣejọba tiwantiwa.

O kẹkọgboye ni fasiti Ibadan ki o to lọ kẹkọ sii lati gba iwe ẹri olukọni ni fasili Hull lorilẹede UK. Lẹyin eyi o tun kawe sii lati gboye imọ ijinlẹ Masters nipa akoso eto ẹkọ ati iṣakoso ie ẹkọ ni fasiti Macquarie lorilẹede Australia.

O ṣiṣẹ olukọ ni ileẹkọ girama Ondo Boys High school atawọn ile ẹkọ miran lagbegbe Ondo ati Akurẹ. Lẹyin igba diẹ loun pẹlu da ile ẹkọ ara rẹ silẹ ninu eyi ti a ti ri Ọmọlere Nursery and Primary School, Akurẹ High School ati St Frances' Academy ni Igoba nilu Akurẹ.

Irinajo oṣelu rẹ wa ni ipẹkinpẹki pẹlu irinajo Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ; ilana oṣelu Awo lo si mu dani to fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Action Group nigba naa ki o to di Unity Party of Nigeria.

Laarin ọdun 1979 and 1983, Ọgbẹni Fasoranti di ipo kọmiṣọna fun eto iṣuna labẹ ijọba gomina Adekunle Ajaṣin ni abẹ ipinlẹ Ondo laye ọjọun.

Lẹyin eyi loun pẹlu di ọkan lara awọn aṣiwaju lẹgbẹ Afẹnifẹre, to jẹ ẹgbẹ kan gboogi to duro lori ilana Awolọwọ.

Ipa to ko lasiko ijangbara fun ijọba alagbada

Baba Fasoranti jẹ ọkan gboogi lara awọn to koju ologun fun idapada ijọba alagbada loriede Naijiria.

Ipinnu rẹ lo sọ ọ di ẹni to n darapọ mọ ẹgbẹ NADECO to lewaju didoju kọ ijọba ologun lati da ijọba pada fun alagbada laaarin ọdun 1993 si 1999.

O pada wa di olori ẹgbẹ Afẹnifẹre lẹyin iku Baba oloye Abraham Adesanya, bi o tilẹ jẹ wi pe ija tani olori to waye laarin oun ati awọn adari ẹgbẹ naa kan pada di oun to mu ipinya wọ aarin ẹgbẹ naa.

"Majẹobajẹ agba lorilẹede ni Baba Fasoranti"

Eeyan kan n tọwọ bọwe ibanikẹdun ni ile Oloogbe Fasoranti.

Lasiko to fi n ṣe ayẹyẹ ajọdun ọjọ ibi ọgọrun ọdun rẹ, aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Tinubu tọka si Baba Fasoranti gẹgẹbi agbalagba to n to ilu, alakoso to dantọ, ajafẹtọ araalu ati ijọba tiwantiwa ti iwa ootọ, ọmọluabi ati ifọkansi ṣiṣe iṣẹ sin ilu.

Aarẹ Tinubu ṣe iranti bi awọn kan ṣe gbiyanju lati gba ẹmi rẹ lasiko iṣejọ ologun labẹ Ọgagun agba Sani Abacha nigba naa. O ni iṣẹlẹ naa tubọ mu ki o ṣe ọkan giri lati koju iwa ijẹgaba awọn ologun.

Awọn ọfọ to ṣẹ ẹ

Oniruuru adanu lo de ba Baba Fasoranti. O padanu iyawo rẹ lọdun 19991. O tun padanu ọmọ rẹ, Funkẹ Ọlakunrin ti awọn agbebọn kan ṣekupa ni oṣu keje ọdun 2019.

Lasiko ajọdun ọjọ ibi rẹ loṣu karun un ọdun 2026, Baba Fasoranti ṣalaye ninu ọrọ to sọ nibẹ pe "Mo ti ri ijọba amunisin, mo ti ri igbominira, oju mi ti ri ogun ati alaafia. Mo ti ri ijọba ologun ati ti alagbada. Ninu gbogbo rẹ ohun kan to mu mi duro ṣinṣin ni ibẹru Ọlọrun, itẹpamọṣẹ ati ṣiṣe iṣẹ sin ọmọlakeji."

O ni irinajo oun pẹlu Afẹnifẹre ti jẹ ki oun mọ laisiyemeji pe ifaraẹnijin nikan lohun ti wọn n pe ni ipo adari

Ààrẹ ẹgbẹ́ Afẹnifẹre, Reuben Fasoranti jade láyé lẹ́ni ọdún 100
Alagba Reuben Fasoranti nigba to wa laye

Olori ẹgbẹ Afenifere nilẹ Naijiria, Alagba Reuben Famuyide Fasoranti ti jade laye.

Ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 la gbọ pe Alagba Fasoranti ki aye pe o digboṣe, lẹyin aisan to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo.

Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Aiyedetiwa sọ pe adanu nla ni iku baba naa jẹ fun gbogbo ọmọ Kaarọ-o-jiire bi, nitori pe asiko ti wọn nilo rẹ ju, lo jade laye.

"Pẹlu ọkan to wuwo ati jiọwọ fun ifẹ Ọlọrun, mo n kede iku agba alẹnulọrọ, Alagba Reuben Famuyide Fasoranti, ẹni to jade laye lẹni ọgọrun-un ọdun," Aiyedatiwa sọ bẹẹ.

Gomina naa sọ pe agbalagba to ko ipa ribiribi ninu idagbasoke ipinlẹ Ondo, ilẹ Yoruba ati orileede Naijiria lapapọ ni Oloogbe naa.

"Alagba Fasoranti jẹ agba, orison imọ, pẹlu iwa ọtitọ ati ifarajin ti igbe aye pipẹ rẹ tọka si oniruuru ifarajin si idagbasoke ipinlẹ wa, ilẹ Yoruba ati orileede Naijiria lapapọ," gomina fidi rẹ mulẹ.

O tẹsiwaju pe awọn ilana, itọni ati iduro lori otitọ rẹ ni awọn yoo ṣafẹri gidigidi.

Bẹẹ lo sọ pe ipa to fi lelẹ yoo si maa wa nilẹ fun awọn iran to tun n bọ lẹyin.

Bakan naa lo ba idile oloogbe naa kẹdun, to fi mọ gbogbo ilu Akure ati ipijnlẹ Ondo lapapọ kẹdun iku agba alẹnulọrọ ọhun.

"Lorukọ ijọba ipinlẹ yii ati awọn eeyan ipinlẹ Ondo, mo n ba idile, ilu Akurẹ ati gbogbo ipinlẹ yii kẹdun adanu nla yii," gomina kadi ọrọ rẹ nilẹ.

O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere.