Ọlọ́pàá nawọ́ gán èèyàn 135 bí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ṣe ń tẹ̀síwájú ní France

Ọkunrin to fi aṣọ boju, o gbe aga lọwọ, awọn ero wa lẹyin rẹ, ti eefi si boju titi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko din ni eeyan marundinlaadoje to ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa bayii bawọn oluwọde ṣe n fọhonuhan ni orilẹ ede France.

Awọn fidio to wa lori ayelujara ṣafihan bawọn oluwọde naa ṣe n sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si n fọwọ bo ẹnu ati imu lẹyin tawọn ọlọpaa yin afẹfẹ tajutaju gaasi si wọn ni Lyon.

Awọn ọlọpaa ni Bordeaux, guusu France sọ pe niṣe ni awọn oluwọde kan n ju awọn nnkan oloro sawọn ọlọpaa, ti wọn si n ṣe ikọlu sawọn ẹṣọ aabo.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣekilọ fawọn araalu atawọn oluwọde lati jina sawọn ibi ti wọn mọ odi si, ki wọn si ri pe awọn ko tayọ awọn ibi ti wọn gba wọn laaye lati ṣe iwọde de.

Awọn fidio to wa lori ayelujara ṣafihan awọn eeyan to wọ aṣọ dudu, fi aṣọ boju, ti wọn n kuro lati ibi ile kan.

Awọn alaṣẹ ni Gironde, guusu iwọ oorun France, sọ pe eeyan mẹtala ni wọn ri to gbe awọn ohun ija oloro dani lasiko iwọde nibi iwọde lagbegbe naa.

Lara awọn aworan to jade loju opo X ṣafihan ibọwọ, iboju atawọn ohun imi.

Kaakiri awọn agbegbe ni France nibi ti iwọde ti n waye ni wọn ti n fi afẹfẹ tajutaju gaasi le awọn oluwọde kuro nibi iwọde.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yatọ si Lyon, niṣe ni wọn tun fi afẹfẹ gaasi le awọn oluwọde ni Marseille.

Ọkan lara awọn oluwọde naa sọ pe awọn bii aadọjọ, ti ọpọ wọn jẹ akẹkọọ ile ẹkọ girama ati ile ẹkọ giga fasiti ni wọn fi afẹfẹ tajutaju le kuro nibi iwọde ni Lyon.

Iwe iroyin France kan, Le Parisien sọ pe awọn ọlọpaa lo afẹfẹ gaasi tajutaju lati fi tu awọn oluwọde ka ni Nice, Clermont-Ferrand ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn lo afẹfẹ tajutaju lati tu awọn oluwọde ka nigba tawọn oluwọde naa n kọja awọn ibi to yẹ ni Nantes.

Ọkan lara awọn oluwọde naa ni Paris sọ fun BBC pe iwọde maa tẹsiwaju titi ti aarẹ Emmanuel Macron fi maa gbọ ohun tawọn oluwọde n beere fun.

Zelie, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, sọ pe awọn eeyan n ṣe ọde nitori iya to n jẹ awọn eeyan lati igba ti Macron ti wa nipo.

"Wọn n pawa lẹnu mọ, wọn n gba owo wa, owo ori ti a n san pọ pupọ, a o si le ṣe ohunkohun."

Zelie tẹmpẹlẹmọ pe ọpọ awọn olukọ ni iṣẹ ati oṣi n ba finra, to si juwe ile ẹkọ rẹ bi ọkan lara awọn to buru julọ ni France.

O sọ pe ikẹkọọ ni France buru gidi gan, eyi to mu ko ṣoro fawọn akẹkọọ lati le kẹkọọ akọye .

Macron nilo lati mọ pe o gbọdọ bẹrẹ si ni gbe igbesẹ nitori oun ko mọ boya ọjọ ọla oun dara ni France nitori a tib ii oṣu mẹfa ni oun ti n wa iṣẹ amọ ti ko si iṣẹ fun oun.

Ẹni ọdun mejidinlogun mii ti oun naa n kopa ninu iwọde naa sọ pe niṣe lo dabi pe ijọba Macron ko ṣe ohunkohun fun awọn.

O bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan ṣe n ja ṣọọbu awọn eeyan mii nibi iwọde naa amọ to woye iṣẹ ati oṣi to n ba awọn eeyan finra lo ṣokunfa rẹ.

Nigba to n sọrọ lori igba ti iwọde naa maa wa sopin, o sọ pe erongba awọn ni ki ijọba dahun gbogbo ibeere awọn.

"A n fẹ ayipada rere ni France."

Ileeṣe ọlọpaa ni eeyan to le ni 130,000 lo ṣe iwọde ni France nigbati awọn to le ni ẹgbẹrun mẹtala lọ ṣe iwọde alaafia ni Orléans.