Balogun Ogbomoso: Kí ló ń fa gbas gbos láàárín Soun Ogbomoso àti ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo?

Gomina Seyi Makinde wa laaarin Ọba Ghandi Olaoye ati Oloye Dokita saka Balogun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Niṣe ni awuyewuye ṣuyọ laaarin ijọba ipinlẹ Oyo ati Soun ti ilu ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye lori iyọnipọ Dokita Saka Adigbite Balogun gẹgẹ bi Balogun ilu Ogbomoso.

Atẹjade ti Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye ni ipinlẹ Oyo, Ademola Ojo sọ pe gomina nikan lo ni aṣẹ lati yọ oloye to ba wa ni ipo giga bii ti Balogun naa nipo, pe Soun ko ni aṣẹ kankan lati rọ oloye naa nipo rẹ.

Ojo fidi rẹ mulẹ pe abala kẹrindinlọgbọn iwe ofin to de awọn oloye ati ọba alaye ni ipinlẹ Oyo ko fun Soun laaye lati gbe igbesẹ rirọ oloye to wa ni ipo Balogun loye, to si ni igbesẹ naa lodi sofin.

O ni fun idi eyi, Dokita Saka Adegbite ṣi ni Balogun ti ilu Ogbomoso, to si rọ awọn eeyan lati kọti ọgbọin si iroyin pe wọn ti rọ Balogun naa loye kuro nipo rẹ.

Ki lo fa awuyewuye yii?

Ifanfa yii lo n waye lẹyin ti aafin Soun Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye fi atẹjade kan lede pe awọn ti ni ki Dokita Saka Adigbite Balogun lọ rọkun nile gẹgẹ bi Balogun ilu Ogbomoso fun igba kan na lai ni gbedeke.

Ẹsun ti wọn fi kan Balogun naa ni pe o kọ lati tọwọbọ iwe adehun ati ibura jijẹ olootọ si Soun lati oṣu mẹwaa ti wọn ti yan-an loye.

Ninu atẹjade naa ni Aafin Ogbomoso ti sọ pe bibuwọlu iwe ibura ati adehun naa jẹ ọkan lara awọn ohun to ṣe Pataki fun ẹni to ba jẹ oloye Balogun lati buwọlu.

Wọn fẹsun kan pe ọpọlọpọ iwe iranti ni awọn ti kọ ranṣẹ si Balogun naa lati fi ran leti lati ṣe ojuṣe ṣugbọn to kọ lati buwọlu iwe adehun naa.

Wọn ni eyi lo mu Ọba Olaoye lati paṣẹ pe ki Dokita Balogun ye pe ara rẹ ni Balogun Ogbomoso mọ titi ti wọn fi maa ṣagbeyẹwo ofin to de bi wọn ṣe ni ko lọ rọkun nile.

Amọ idasi ijọba ipinlẹ naa bayii ti wa yi aṣẹ Soun naa pada ti wọn si ni Dokita Saka Adigbite Balogun ṣi ni Balogun ilu Ogbomoso.

A kan ni Dokita Saka Balogun lọ rọkun nile ni, a o yọ ọ nipo - Aafin Ogbomoso

Lẹyin atẹjade ijọba ipinlẹ naa ni Aafin Ogbomoso tun fi atẹjade mii sita lati ṣalaye ọrọ lori ọrọ oye naa.

Atẹjade naa sọ pe Aafin ko rọ oloye naa nipo bikoṣe pe wọn ni ko lọ rọkun nile fun igba kan ni.

Wọn ni eyi lodi to gba igboro pe Soun rọ oloye naa nipo rẹ.

Atẹjade naa ṣalaye pe idi ti wọn fi ni ki oloye naa lọrọkun nile ko ṣẹyin pe ko ṣe ojuṣe rẹ nipa bibuwọlu iwe ibura ati adehun ti awọn oloye mii laafin buwọlu.

"Oṣu mẹwaa ni Aafin Soun fi duro ki oloye Balogun fi buwọlu iwe naa amọ to kọ lati buwọlu u.

"Kaka ko ṣe bẹẹ niṣe lo n bu Soun ati ipo ọba Ogbomoso kaakiri, to si n sọ awọn ọrọ ti ko dara nipa Soun lo ṣokunfa sisọ fun pe ko lọ rọkun nile.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe bi oloye naa ṣe kọ lati buwọlu iwe naa fi han pe ko jẹ olootọ si Soun ti awọn ko si le fi aaye gba iru afojudi bẹẹ.