Àlàyé rèé lórí bí ògbóǹtarìgì agbésùnmọ̀mí, Muhammadu-Filani, ṣe rí ikú hé lọ́dọ̀ ológun tó gba onírúurú ìbọn lọ́wọ́ rẹ̀

Oku agbesunmọmi nilẹ pẹlu oriṣiiriṣii ibọn

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ikọ ọmogun Operation FANSAN YAMMA ti ṣekupa Kachalla Muhammadu Filani, ogbontarigi agbesunmọmi kan lapa iwọ oorun ariwa Naijiria, wọn si gba oriṣiiriṣii ibọn, ohun ija oloro atawọn alupupu lọwọ rẹ.

Lasiko tawọn ikọ ologun naa n ṣiṣẹ ni ijọba ibilẹ Matazu nipinlẹ Katsina ni wọn ṣe aṣeyọri ọhun.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii gan an ni wọn yabo ibuba agbesunmọmi naa.

Agbẹnusọ fun ikọ ologun JTF, Ọgagun Aliyu Danja, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe awọn agbesunmọmi kọju ija sawọn ọmogun Operation Fansan Yamma nigba ti wọn yabo ibuba ogbontarigi agbesunmọmi naa.

Ọgagun Danja ṣalaye pe awọn ọmogun Naijiria lo pada ṣegun awọn agbesunmọmi naa ti ọpọ wọn si fẹsẹ fẹẹ.

Agbẹsnusọ JTF sọ pe ikọ ọmogun Naijiria gba ibọn ''machine gun'' mẹta, ibọn AK-47 meji, apo iko ọta si mọkanla ati ọta ọgọsan an lọwọ awọn janduku agbebọn naa.

Ọgagun Danja sọ pe bi ọwọ ṣe tẹ ogbontarigi agbesunmọmi naa ko ṣẹyin bi ikọ Operation Fansan Yamma ṣe n ṣakitiyan lati finna mọ awọn agbesunmọmi nibi gbogbo ti wọn ti n ṣọṣẹ lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria.

O ni awọn ọmogun ṣetan lati jẹ ki alaafia jọba pada lawọn agbegbe tawọn janduku agbebọn ti n ṣọṣẹ.

''Awọn ọmogun wa ni digbi lati kọju ija sawọn agbesunmọmi, lati finna mọ wọn ati lati ri pe alaafia jọba lawọn agbegbe ti wọn ti n ṣoṣẹ,'' Danja lo sọ bẹẹ.