Wo ìdí mẹ́ta tí akẹ́kọ̀ọ́ tí ilé ẹ̀kọ́ ti gbà wọlè le má rìí orúkọ rẹ̀ lójú òpó JAMB àtàwọn ìgbésẹ̀ tò yẹ kó o gbé

Oríṣun àwòrán, Jamb Help center
Ajọ to n ri si eto idanwo sile ẹkọ giga iyẹn Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB) ti darukọ nnkan mẹta to le mu ki awọn to ba ṣe idanwo lati ma ri orukọ wọn lori orukọ ti ajọ naa gbe jade.
JAMB ninu alaye kan ti wọn gbe soju opo ayelujara X wọn ṣalaye pe o ṣeeṣe ki eeyan ti ile ẹkọ to ṣe idanwo lati lọ gba a wọle amọ ki wọn ma ri loju opo JAMB pe wọn ti gba a sile ẹkọ naa ati pe awọn nnkan mẹta lo maa n ṣokunfa rẹ.
Wọn ṣalaye pe akọkọ ni ki akẹkọọ bẹẹ ma tẹ ami igbaniwọle loju opo wọn lori Central Admissions Processing System (CAPS) tabi ko jẹ pe o kọ loju opo naa pe wọn ko i tii gba sile ẹkọ kankan.
Jamb gba akẹkọọ ti ko ba ri orukọ rẹ ni oju opo wọn amọ ti ile ẹkọ ti gba wọle nimọran lati pada si ile ẹkọ naa ki wọn ṣamojuto ilana bi wọn ṣe ba a wọle.
Bakan naa ni wọn tun ṣalaye pe ohun to le mu ki orukọ akẹkọọ maa i tii jade loju opo wọn ni ti ile ẹkọ to gba ẹni naa wọle ko ba i tii fi nọmba igbaniwọle akẹkọọ ranṣẹ si JAMB
Wọn ni ki awọn akẹkọọ bẹẹ lọ sile ẹkọ wọn lati jẹ ki wọn gbe eto igbaniwọle gba ilana to tọ, ki wọn si fi orukọ wọn ranṣẹ nipasẹ CAPS.
Wọn fi kun pe ohun to tun le mu ki akẹkọọ ma rii orukọ rẹ loju opo JAMB ni ki akẹkọọ ma tẹ esi idanwo JAMB ati lẹta igbaniwọle rẹ jade.
Wọn fi kun pe awọn akẹkọọ ti ko ba i tii ṣe eyi nilo lati lọ tẹ awọn esi idanwo naa ati lẹta igbaniwọle wọn jade ni ileeṣẹ JAMB tabi ni awọn ileeṣẹ tgi JAMB fọwọ si.
Wọn gba gbogbo awọn akẹkọọ nimọran lati lati tẹle gbogbo awọn ilana to yẹ, ki wọn si maa tẹle ajọ naa loju opo ayelujara lati le maa mọ nipa awọn nnkan to ba n lọ.
Wo àlàyé bí o ṣe lè fi èsì ìdánwò O'level rẹ ṣọwọ́ sí JAMB láì kúrò nínú ilé rẹ
Awọn akẹkọọjade ile ẹkọ girama ni Naijiria ti le fi esi idanwo O'level wọn ṣọwọ si oju opo JAMB bayii lai kuro ninu ile wọn.
Alaga fidihẹ JAMB, Fabian Benjamin lo fi ikede naa lede loju opo X ajọ ọhun lọjọ Aje.
Benjamin sọ pe ajọ naa ti ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ajọ to n ri si idanwo WAEC ati WASCE lori esi idanwọ awọn akẹkọọ naa.
O ni awọn akẹkọọ le fi esi idanwo ipari ile ẹkọ girama wọn ṣọwọ si JAMB bayii ti JAMB yoo si fi ontẹ lu esi naa pẹlu awọn ajọ idanwo girama to ku.
Gẹge bo ṣe sọ, igbesẹ naa waye lọna ati mu ki nnkan rọrun fum awọn akẹkọọ.
Bi o ṣe le fi ontẹ lu esi idanwo O'Level rẹ lati ile

Oríṣun àwòrán, JAMB
Iwọyi lawọn igbesẹ ti o gbọdọ gbe lati fi esi idanwo rẹ ṣọwọ si JAMB lai kuro ninu ile rẹ.
- Lọ soju opo buyresultsverificationcode.ng.
- Tẹ nọmba NIN rẹ si aye ti wọn fi sibẹ ki o tẹ "Verify NIN"
- Kọ iye igba ti o joko lati kọ idanwo naa ati ajọ to bojuto idanwo bii WAEC tabi NECO
- Tẹ "Continue" lati tẹsiwaju
- Kọ ajiṣẹ email ati nọmba ẹrọ ilewọ rẹ ki o si tẹ "Pay Now" lati san owo
- Eyii yoo gbe ọ lọ si ibi ti o ti maa san owo
- San owo ti wọn bere pẹlu kaadi ATM rẹ tabi nipa ọna mii
- Lẹyin ti owo naa ba ti lọ tan, tẹ nọmba idanimọ idanwo rẹ, irufẹ idanwo to jẹ ati ọdun ti o kọ idanwo naa
- Bi o ṣe le fi esi idanwo O'Level rẹ si oju opo naa
- Lọ sori ẹrọ ilewọ rẹ ki o si fi "VERIFY" ṣọwọ si 55019 tabi 66019
- Esi idanwo naa yoo lọ, ajọ naa yoo si kan si ọ
- Awọn ti wọn kọ idanwo naa ju ẹẹkan lọ yoo gba ipe lati lọ soju JAMB e-Facility
- Loju opo JAMB e-Facility, tẹ "2026 UTME O'Level Upload"
- Kọ Verification Code rẹ sibẹ, yoo si gbe esi idanwo ti o ṣe lẹẹmeji naa jade
- Tẹ awọn ẹka idanwo ti o ṣe ki o si tẹ "Apply the O'Level Results" lẹyin naa
Ti esi idanwo ọhun ba ti lọ, JAMB yoo jẹ ki o mọ.
Ninu ọrọ Benjamin, o ni ajọ JAMB yoo tẹsiwaju lati maa lo imọ ẹrọ fun idanwo, yoo si tẹsiwaju lati maa ba awọn ajọ idanwo mii ṣiṣẹ papọ fun anfani awọn akẹkọọ.



























