'Nítorí pé èèyàn kan fi mí we ọ̀bọ ló jẹ́ kí n lọ bóra'

Oríṣun àwòrán, REALOMOJINAD/INSTAGRAM
Gbajumọ oṣere tiata, Habibat Jinadu ti sọ pe nitori a ti maa ri iṣẹ gba ni oun fi lo ipara lati fi bora.
O ni nigba ti oun bẹrẹ ere tiata, ti awọn ba nibi ti awọn ti fẹ ya fiimu, niṣe ni wọn maa n sọrọ si oun pe oun ti dudu ju, ti wọn si maa n nilo ina rẹpẹtẹ lati fi ya iṣẹ ti oun ba wa.
O ṣalaye pe ọpọ igba ti wọn ba n sọrọ si oun yii ni oun kii ka a kun ayafi ọjọ ti eeyan kan fi oun we ọbọ.
O ni lasiko igba naa, awọn eeyan to ba pupa ni wọn maa n pe si iṣẹ eyi to mu oun naa pinnu lati lọ bora ki oun naa le maa ri iṣẹ gba.
"Ti o o ba pupa, wọn o ni fun ẹ niṣẹ, ti o o ba sanra naa, wọn o ni fun eeyan lo jẹ ki n sọ pe jẹ n lọ bo o jare boya wọn a fi eeyan lọkan balẹ."
"Ti o o ba pupa, wọn o ni fun ẹ niṣẹ, ti o o ba sanra naa, wọn o ni fun eeyan lo jẹ ki n sọ pe jẹ n lọ bo o jare boya wọn a fi eeyan lọkan balẹ."
Jinadu sọ pe lẹyin ti oun bora lootọ ni oun bẹrẹ si ni ri iṣẹ gba daadaa amọ ọpọ eeyan ni ko da oun mọ mọ ti wọn ba ri oun.
O sọ pe ọpọ eeyan ti wọn ba ri oun ni wọn maa n sọ fun oun pe oun jọ ẹni mimọ, ti oun si maa n ro o ninu ara oun pe ki lo de ti awọn eeyan ko da oun mọ pẹlu bi oun ṣe pupa.
O fi kun pe inu oun ko dun si bi oun ṣe bora naa amọ oun n farada a nitori ki oun le maa ri iṣẹ ṣe.
O sọ nigba to ya ni oun ro o funra oun pe oun nilo lati fopin si ipara ibora ti oun n lo paapaa bi oun ṣe bẹrẹ si ni fi ara ya ni gbogbo igba.
"Mo kan bẹrẹ si ni fi ara ya, mo bẹrẹ si ni fara ṣeṣe, mo bẹrẹ si maa lapaa loriṣiriṣi, nnkan kekere bayii, ara mi ti ya, mo ti legbo.
"Inu mi o dun. Nigba to ya ẹmi yẹn sọ fun mi pe wọn n sọ fun ẹ pe ko o ṣe idaduro kini yii amọ o o fẹ gbọ amọ mi o gbọ."
Oniruuru eebu ni awọn eeyan bu mi nigba ti mi o bora mọ
Jinadu tẹsiwaju pe nigba to ya ti oun loyun ọmọ oun lọdun 2023, ti oun ko ri bi lo ipara lati fi bora ni oun ara bibo silẹ patapata.
O ni lẹyin ti oun bimọ tan ni ọkan lara awọn akẹgbẹ oun, Adunniade ṣe abẹwo si oun to si sọ fun oun pe ki oun ye bora mọ nitori awọ ara oun rẹwa lai lo awọn ipara ibora naa.
O sọ pe eyi lo mu oun lati ma lo ipara naa mọ amọ oniruuru awọn nnkan ni oun koju nigba ti oun fi ipara silẹ.
"Ha! iya n jẹ ọta ẹ ni, ko rowo ra ipara mọ ni, ta lo lọ fẹ to n fiya jẹ ko si n nnkan tawọn eeyan o sọ nigba ti mo sọ pe mi o bora mọ."
O ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun, to si gbadura pe ki Ọlọrun dariji oun pẹlu gbogbo nnkan ti oun ti ṣe sẹyin.

























