Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Òní Ọjọ́bọ ni Adebutu,Pantami àtàwọn yòókù tí INEC yọ orúkọ wọn yóò mọ ohun tó kàn
Ajọ eleto idibo ilẹ Naijiria; INEC, ti sọ pe oni Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni oun yoo sọ ohun to kan fun awọn oludije sipo oṣelu ti orukọ wọn ko jade fun idibo apapọ ọdun 2027.
Kọmiṣanna apapọ fun ajọ INEC, Mohammed Haruna, lo fidi ẹ mulẹ pe awọn eeyan naa yoo mọ bo ṣe n lọ lonii.
Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ẹka iroyin The Punch l'Ọjọru ni Haruna ti sọrọ naa.
"Fun ti iwe orukọ awọn oludije to gbẹyin, a maa ṣepade lori ẹ l'Ọjọbọ."
Haruna, lo sọ bẹẹ.
Tẹ o ba gbagbe, awọn oludije bii Ladi Adebutu to fẹẹ dupo gomina Ogun, labẹ asia ẹgbẹ PDP, Isa Pantami fun Gombe atawọn mi-in ko ri orukọ wọn ninu akọsilẹ oludije ti INEC gbe jade lọjọ kẹwaa oṣu Kẹwaa ọdun yii.
Ọjọ kẹfa oṣu Keji ọdun 2027 ni idibo sipo gomina yoo waye, bii INEC ṣe fi lede ṣaaju ninu atẹjade wọn.
Awọn yooku ti yoo tun mọ ipin wọn lonii ni:
Aminu Gwarzo, oludije sipo gomina ipinlẹ Kano, ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC).
Danjumah Laah: Kaduna.
Abdullahi Yakubu:SDP.
Musa Zubairu: New Nigeria People's Party.
Ahmed Shuaibu: Action Alliance.
Mohammed Aminu: Accord Party.
Awuyewuye to ṣẹyọ lori orukọ awọn oludije wọnyi ṣi wa nilẹ, awọn ẹgbẹ to kan si n dunkooko lati gbe igbesẹ ofin.
Wọn ni gbogbo eto to yẹ lawọn ṣe, ko si idi kan fun ajọ eleto idibo lati ma ṣe gbe orukọ oludije awọn jade.
Lọwọ yii, ohun ti ọpọ eeyan fẹẹ mọ ni boya INEC ti ṣetan lati da orukọ awọn oludije naa pada, abi wọn yoo ṣe bẹẹ yọ wọn danu raurau.
Awijare INEC lori ai gbe orukọ awọn eeyan naa jade
Lẹyin ti orukọ awọn oludije naa ko si ninu eyi ti INEC fi lede lọjọ Kẹwaa oṣu yii, ajọ naa sọ pe ẹjọ oun kọ rara.
INEC kede nigba naa pe awọn oloṣelu ti orukọ wọn ko jade naa ni ko tete fi iwe orukọ oludije wọn ranṣẹ bi ile ẹjọ ṣe la a kalẹ.
"Ile ẹjọ paṣẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu lati fi iwe orukọ ẹgbẹ wọn ranṣẹ laaarin ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin si ọjọ kẹwaa, oṣu oṣu Karun-un ọdun 2026"
Ajọ naa fi kun un pe awọn ẹgbẹ to kuna lati tẹle ohun ti ile ẹjọ paṣẹ, ko le ni anfaani lati ṣatilẹyin fun eeyan wọn ti orukọ rẹ ko jade.
O ni iwe ti oun gbe jade tẹle wa ni ibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ to ga julọ, ati pe kootu naa fi ọwọ si agbekalẹ orukọ ti oun gbe jade.
Ṣaa, INEC yoo sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ lonii, BBC News Yoruba yoo si mu un wa fun yin bo ba ṣe lọ.