Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Ààrẹ Tinubu dágbére Makkah fọ́mọ Nàíjíríà
Aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti bẹrẹ irin-ajo lati lọ siluu Makkah lorileede Saudi Arabia, lati kopa nibi eto Umrah tawọn ẹlẹsin musulumi maa n ṣe.
Atẹjade ti oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọru, ọsẹ yii.
Onanuga sọ pe Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ni Aarẹ Tinubu yoo gbera lati papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe to wa niluu Abuja.
Ni Makkah ọhun ni Aarẹ Tinubu yoo ti lọ gbadura si Ẹlẹda rẹ lori awọn ohun to n foju sọna fun.
Atẹjade ti Onanuga fi soju opo rẹ, lo ti jẹ ko di mimọ pe irin ajo naa yoo fun Aarẹ Tinubu lanfaani lati ṣe aṣari ẹmi, ifarajin ati adura fun iṣọkan Naijiria.
"Aarẹ Bola Ahmed Tinubu yoo gbera lati ilu Abuja l'Ọjọbọ lọ si Makkah, orileede Saudi Arabia, lati kopa ninu eto Umrah, eyi to nii ṣe pẹlu awọn irin ajo lọ si ilẹ mimọ," Onanuga sọ bẹẹ.
"Irin-ajo naa yoo fun Aarẹ lanfaani lati ṣe aṣaro ẹmi, ifarajin, ati awọn adura fun alaafia, iṣọkan, ati itẹsiwaju orileede Naijiria."
Onanuga fi kun ọrọ rẹ pe, nigba ti Aarẹ Tinubu ba fi wa ni Makkah naa, yoo kopa ninu gbogbo eto patapata to nii ṣe pẹlu Umrah, nibi ti yoo ti wa itọni Allah ati Ibukun fun Naijiria ati awọn eeyan rẹ.
Ṣugbọn sa, ki Aarẹ too gbera fun irin ajo naa, Onanuga jẹ ko di mimọ pe Tinubu yoo fi awọn irinṣẹ ti ileeṣẹ ologun oju ofurufu ṣẹṣẹ ra fun iṣẹ wọn lelẹ ni agbegbe ibi ti Aarẹ yoo ti gbera.
Oludamọran pataki naa wa jẹ ko di mimọ pe ọsẹ to n bọ ni Aarẹ yoo pada si Naijiria, lẹyin to ba pari gbogbo ohun to lọ ṣe.