Ọkọ reluwé méjì kọlu ara wọn, èèyàn 68 kú, ìjọba kéde ọ̀fọ̀ ọjọ́ mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo orileede Spain ni wọn ti wa ninu ọfọ ọlọjọ mẹta bayii, pẹlu bi awọn alakoso ṣe kede ọfọ ọlọjọ mẹta, lori ijamba ọkọ oju irin, iyẹn reluwe to gbẹmi ọpọ awọn eeyan
Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, awọn eeyan ti ko din ni mejidinlaadọrin ni wọn ti padanu ẹmi wọn, lẹyin ijamba naa.
Aarọ Ọjọru, ọsẹ yii ni ijamba naa waye, nigba ti wọn sọ pe reluwee ti ileeṣẹ aladani kan ti wọn pe ni Iryo to n bọ lati ilu Madrid lọ si Seville lọ kọlu reluwee to jẹ ti ijọba.
Gẹgẹ bi a se gbọ, ọkọ reluwe ti Iryo naa lo ko eeyan mẹtadinlaadọjọ (147), nigba ti ọkọ reluwe ti ijọba ko eeyan mẹtadinnirinwo (397).
Gbogbo alẹ Ọjọru, mọjumọ Ọjọbọ ni awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri, to fi mọ awọn eleto ilera fi n ṣiṣẹ lati rii pe wọn ṣe iranwọ to yẹ, paapaa fun awọn to farapa.
Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn to padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọhun, ni awọn alakoso sọ pe wọn ko tii mọ orukọ wọn, tabi ibi ti wọn n gbe, ṣugbọn ti wọn sọ pe iṣẹ iwadii n lọ lọwọ.
Awọn alakoso sọ pe yatọ si eyi, awọn tun ṣi n ṣe iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa ijamba naa.
Olootu ijọba ilẹ Spain, Pedro Sánchez sọ pe asiko ọfọ ati adanu ni orileede naa wa bayii, pẹlu bo ṣe sọ pe ọpọ ẹmi lo ti sọnu.
Sánchez jẹ ko di mimọ pe ọpọ mọlẹbi ni wọn ti wa ninu ibanujẹ, to si jẹ pe ibanujẹ naa ko ṣee gbagbe.
Bakan naa ni minisita fọrọ ohun abẹle sọ pe ọgunlọgọ awọn oṣiṣẹ loriṣiriṣi ni wọn ti ran lọ sibi iṣẹlẹ naa lati ṣe iranwọ to yẹ fun awọn to ku, ati awọn to farapa.
O ni awọn ẹrọ igbalode 'drones' ati ọkọ baalu agberapa, ni wọn ti ko lọ sibẹ lati wa awọn to fara kaaṣa, ki wọn si le yọ wọn kuro ninu ijamba naa.
Kí ló fa ìjàmbà yìí?
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọkọ reluwe to jẹ ti ileeṣẹ Iryo ni wọn lo daṣẹ silẹ lori irin.
Minisita feto irinna, Óscar Puente sọ pe ẹrọ kọmputa to n gbe reluwe naa ṣiṣẹ lo daṣẹ silẹ loju ọna.
O sọ pe nigba ti ọkọ reluwe ba daṣẹ silẹ, o di dandan ki awọn awọn alakoso lati Madrid bẹrẹ iṣẹ iṣakoso rẹ fun wakati mẹrinlelogun, ṣugbọn to ni awọn wọnyi ti gbe igbesẹ to ku diẹ kaato.
O sọ pe niṣe ni wọn sọ fawọn to n tukọ reluwe naa lati bẹrẹ iṣẹ pada, lai fi gbedeke bi yoo ti ṣe sare to si i.
Bakan naa la gbọ pe akaalẹ ohun (audio recordings) kan to ṣafihan ajọsọ laaarin awọn alakoso reluwe naa ni Madrid ati awọn to n wa reluwe ọhun, nibi ti wọn ti fun reluwe kan ni aṣẹ lati rin pẹlu ọpọlọpọ ere sisa, pẹlu bi wọn ṣe mọ pe reluwe kan ṣi taku niwaju soju ọna naa.
Iryo sọ pe lati ẹyin ni reluwe ti ijọba, Renfe to n bọ naa ti gba reluwe wọn.
Wọn ṣalaye pe gbogbo ile kọọkan ti reluwe naa lo ṣubu kuro loju irin rẹ.
Kí làwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ?
Lara awọn ti ijamba naa ṣoju wọn sọ pe awọn ri awọn eeyan ti wọn n sunkun, ti wọn si n da ẹjẹ.
Wọn ni awọn to wa ninu reluwe naa ko le kuro lori ijokoo wọn, depodepo wi pe wọn yoo jade sita, titi digba ti ina fi ṣẹyọ.
Olootu ijọba Spain, Sánchez wa sọ pe ohun ti ko jẹ itẹwọgba ni ki ijamba reluwe meji ṣẹlẹ laaarin ninu ọdun yii.
Sánchez sọ pe ijamba ọkọ reluwe kan ti ṣẹlẹ ninu oṣu Kinni, ọdun yii, to si mu ẹmi awọn mẹrindinlaadọta lọ nitosi Córdoba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn olóṣèlú wọ́gilé ìpolongo òṣèlú
Pupọ awọn ẹgbẹ oṣelu ni wọn ti wọgile eto ipolongo idibo to n bọ lọna, lati kẹdun ikọlu naa, yatọ si ẹgbẹ oṣelu Vox.
Olori ẹgbẹ oṣelu naa, Santiago Abascal sọ pe awọn ko le tori ijamba naa lati gboju kuro ninu awọn ojuṣe wọn.
Mojumọ, awọn to ti ẹgbẹrun kan ataabọ ni wọn korajọ siwaju ileeṣẹ to n ri sọrọ eto irinna, Spanish Transport Ministry, nibi ti wọn ti n pe fun ikọwefipo silẹ Sánchez ati Puente.
Awọn ọlọpaa, nibi ikorajọ naa ni wọn ti fin afẹfẹ tajutaju lati le gbogbo awọn eeyan naa kuro, bo tilẹ jẹ pe wọn ko mu ẹnikẹni, bẹẹ ni ko sẹni to farapa.
Àwọn awakọ̀ reluwé yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì
O ṣee ṣe ki awọn awakọ reluwe bẹrẹ iyanṣẹlodi l'Ọjọbọ ti wọn ti n gbero tẹlẹ, pẹlu bi ẹgbẹ awọn awakọ reluwe, Spanish Union of Railway Drivers (Semaf) ṣe n sọ pe awọn yoo bẹrẹ, "lati fi beere fun aabo reluwe".
Olori ẹgbẹ oṣelu alatako ni Spain, People's Party, Alberto Núñez Feijóo sọ pe: "Spain ni ẹtọ lati mọ nipa awọn ohun to n ṣẹlẹ si awọn ohun ini rẹ."
Ṣugbọn ṣa, lalẹ Ọjọru, awọn mọlẹbi kan ṣi n gbiyanju lati mọ nipa awọn to wa ninu reluwe lasiko ijamba naa.
Sibẹsibẹ, ileeṣẹ Spanish Civil Guard ti gbe ileeṣẹ rẹ dide ni Madrid, Toledo, Seville ati Córdoba lati ṣe iwadii nipa awọn ti wọn n wa.
Ni Toledo, nitosi ibi ijamba naa, awọn eeyan dide iṣẹju kan lati fi bu ọla fun awọn to fara kaaṣa lasiko iṣọ oru ti wọn ṣe.
Ijamba yoo ni yoo jẹ eyi to buru julọ ti orileede naa ti koju, lẹyin eyi to ṣẹlẹ lọdun 2013 nibi ti awọn ọgọrin eeyan ti ku ni Santiago de Compostela, ẹkun Ariwa-Guusu Spain.

























